Home / Àṣà Oòduà / “Iyawo mi n yale, o tun bimo ale fun mi”: Alabi yari ni kootu Ikorodu

“Iyawo mi n yale, o tun bimo ale fun mi”: Alabi yari ni kootu Ikorodu

Orisun

 

Ogbeni Alabi Rasheed, eni odun mejidinlaadota (48) ti gbe iyawo re, Sherifat, lo si ile ejo lati tu yigi igbeyawo odun mewaa to wa laaarin won ka lOjobo ose to koja yii. Gege bi alaye Alabi ni Ikorodu Customary Court to kale siluu Eko, oko Sherifat salaye fun ile ejo wi pe ayewo eje ti oun se fun awon omo oun fi da oun loju wi pe omo ale ni omo keji ti iyawo oun bi foun.

Ogbeni Alabi to n gbe ni oju ona Baiyeku to wa n’Igbogbo si n ro ile ejo naa lati fi obe ja okun igbeyawo naa si meji, ki onikaluku si maa gba ibi tie lo ni alaafia.

“Aja igboro ni iyawo mi, ‘sokisoki’ lo ma n se kiri igboro. Bakan naa si ni awon ale re o lonka. Iwa re yii lo je ki n lo se ayewo eje fun awon omo meji to bi fun mi. Ayewo DNA ti mo si se fi ye mi wi pe omokeji ti iyawo mi bi fun mi kii se omo mi rara- omo ale ni.

“Yato si eleyii, oro re ti su mi. O kan an doju ti mi kiri adugbo lasan ni. Gbese jije re ti poju. Gbogbo ara adugbo lo ti yawo lowo won tan lai da okankan pada. Aimoye igba ni awon olopaa ti wa gbe lori esun gbese yii naa ni bi eni won fi se,” Alabi se bee lalaye.

Awon Yoruba bo, won ni agbejo eni kan da, agba osika ni i se. Onidajo fun Sherifat, eni odun mejilelogoji (42) naa lanfaani lati so tenu re. Sherifat ni iro gbaa ni gbogbo alaye ti oko re ro kale. O ni oko oun feran ejo wewe, o si tun je enikan to maa n gbe ara re lokan soke lai nidi kan pataki.

“Oko mi ko so fun wi pe oun fe lo se ayewo eje nigba to ko awon omo mi kuro nile, ohun to so ni wi pe, oun fe ko won lo sibi ayeye ojo ibi.

“Mi o gba oro re gbo wi pe lotito lo lo se ayewo eje fun awon omo naa. O kan an wa ohun kewo lati ba igbeyawo yii je lasan ni.

“Kosi igbeyawo ti ko ni ipenija tie, maa si fi asiko yii ro ile ejo yii lati ba wa wa atunse si oro to wa nile yii, ti igbeyawo aladun yii ko fi ni fori sanpon lai ro tele,” Sherifat se alaye tie naa.

Onidajo Omolara Abiola to n joko ni kootu naa pase wi pe ki won lo tun ayewo naa se fun idaniloju . Bakan naa lo sun igbejo naa di ojo keji osu kejila, 2/12/2015.

Iroyin Lati Ọwọ Olayemi Olatilewa

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo