Home / Àṣà Oòduà / Nnkan méje ti yóò yipada àti meje ti kò ni yi pada lẹ́yìn ti ilẹ Gẹ̀ẹ́si ti kuro labẹ EU

Nnkan méje ti yóò yipada àti meje ti kò ni yi pada lẹ́yìn ti ilẹ Gẹ̀ẹ́si ti kuro labẹ EU

Ǹkan méje ti yóò yipada àti meje ti kò ni yi pada lẹ́yìn ti ilẹ Gẹ̀ẹ́si ti kuro labẹ EU

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lẹ́yin ọdún mẹ́ta lílọ bibọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Brexit, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì padà kúrò lábẹ́ EU ní aago mọ́kànlá alẹ́ ọjọ́ Jimọ ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n Oṣù kínní ọdún 2020.

Láàrin yìí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì yóò sì máa tèlé àwọn òfin EU bákan náà ni wọ́n á máa san owó tí ó yẹ. Àwọn ǹkan yóò jọra wọ́n sùgbọ́n àwọn míràn yóò máa yí padà.

1.Gbogbo àwọn asojú ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì yóò pàdánù ààyè wọn ní EU

Adarí ẹgbẹ́ Brexit, Nigel Farage jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbétẹrù tó ní pé kí Uk fi EU sílẹ̀ náà sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn asojú mẹ́taleláàdọrin tí yóò pàdánù ààye wọn ní ilé Aṣòfin Yuropu.

Èyí túmọ̀ sí pé lọ́wọ́lọ́wọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì yóò fi gbogbo ètò òṣèlú àti àwọn àjọ tó jẹ́ ti EU sílẹ̀

2.Kò sí àpérò European Union mọ́

Asojú Ìjọba Ilẹ Gẹ̀ẹ́ṣì Boris Johnson yóó ní láti gba ìwé ìpe kó tó yọjú síbi àpérò EU lọ́jọ́ iwájú.

Bákan náà àwọn mínísítà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì kò ní le péjú síbi àpérò tó ní ṣe pẹ̀lú ètò kankan.

3. A ó máa gbọ́ nǹkan tí ó pọ̀ nípa òwò

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì yóó le má a bá àwọn orílẹ̀èdè míràn lágbàáyé sọ̀rọ̀ nípa Ìlànà tuntun lórí káràkátà.

Ṣaájú àsìkò yìí UK kò ní àǹfànì láti se àdéhùn Ìdókoòwò pẹ̀lú orílẹ̀-èdè míràn bí i US àti Australia ṣe ń se, lásìkò tí wọ́n wà lábẹ́ EU.

Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ìdí tí wọ́n fi kúrò ní EU , nítorí wọ́n fẹ́ ní oore-ọ̀fẹ́ láti ṣe nǹkan wọn fúnrawọn.

Tí wọ́n bá tí ẹ̀ lu àlùyọ láti dóko-òwò pẹ̀lú orílẹ̀-èdè kan, wọ́n kò ní le se títí tí àsìkò tí won yóó fi kúrò ní EU pátápáta

4. Ìwé ìrìna UK yóó pààrọ̀ àwọ̀

Ìwé ìrìnà àlàwọ̀ omi aró yóò padà wá lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún tí wọ́n ti yíi padà sí àwọ̀ tí wọ́n n lò lọ́wọ́ báyìí.

Ìpolongo yìí wáye lọ́dun 2017 láti padà sí aláwọ̀ búlúù tí wọ́n ó lò ní ọdún 2021.

5. Owó Brexit
Ó tó mílíọ̀nù mẹ́ta owó brexit tí wọ́n kọ déètì ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kínní lé lórí tí wọ́n sì kọ àkọlé “Peace, prosperity and friendship with all nations”, yóó bẹ̀rẹ̀ sí ní di níná ní ọjọ́ Jimọ.

Ọ̀pọ̀ ló ti tako owó náà tí wọ́n sì láwọn kò fọwọ́ sí i.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn owó ẹyọ náà ni wọ́n ti dá padà, tí wọ́n sì ti fi ṣe nǹkan míràn lẹ́yìn tí àsìkò tí wọ́n dá ti kọjá

6. Ẹ̀ka Brexit ti parí ojúse wọn, abala náà yóó kógbá sílé

Àwọn ìgbìmọ̀ tó ń mójútó bí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì sẹ lo sí Brexit ti di títúká báyìí.

Ẹ̀ka tó mójútó kíkúrò ní EU tí asojú Ìjọba tẹ́lẹ̀ Theresa May dá sílẹ̀ lọ́dún 2016 náà yóó kúrò nípò

Tí àpérò kankan bá jẹyọ lọ́jọ́ iwájú, àwon alágbàwí UK yóó ma fi Downing Street ṣe olú ilé iṣẹ́ wọn.

7. Orilẹ̀-èdè Germany kò ní fi àwọn ọ̀daràn ránṣẹ́ sí UK

kò ní ṣeéṣe fún àwọn ọdanran kan láti padà sí UK tí wọ́n bá ti fi ìgbà kan ṣá lọ sí Germany tẹ́lẹ̀.

Orílẹ̀ -èdè Germany kìí gbà kí wọ́n mú ọmọ ìlú rẹ̀ lọ sí orilẹ̀-èdè tó bá yàtọ̀ sí èyí tó wà lábẹ EU.

Kò tí dáju bóyá irú rẹ̀ náà le ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè míràn bíi Slovania.

Nítorí pé ìsípò padà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì bẹ̀rẹ̀ lóní wàràǹsesà, àwọn nǹkan mìíràn kò ní yí padà, ó kéré tán títí di inú oṣù kejìlá ọdún 2020.

1. Ìrìn Àjò
Ọkọ̀ òfurufú àti reluwé yóò ma ṣe iṣẹ́ bí ó ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀.

Lásìkò ìsípò padà , àwọn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì yóó sì má tò sí ibi tí wọ́n pèsè fún àwọn ọmọ EU nìkan

2. Ìwé ìwakọ̀, ìwé níní ǹkan ọ̀sìn

Níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ pé kò ti lùgbàdi àkókò

3. Káàdì European Health Insurance (EHIC)
Káàdì yìí ni wọ́n má fi ń gba ìtọ́jú yálà tí ènìyàn bá ṣe àìsàn tàbí wọ́n ní ìjàmbá kan tàbí òmíràn

Wọ́n le lọ ní orílẹ̀-èdè tó bá wà ní abẹ́ EU, ni Switzerland, Norway, Iceland àti Liechtenstein, èyí yóó sì máa siṣẹ́ lọ títí wọ́n yóó fi sípò padà tán.

4. Wọ́n le máa siṣẹ́ kí wọ́n máa gbé ní EU
Òmìnira wà fún láti yan sí ibi tó bá wù wọ́n lásìkò ìsípò padà, àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì yóó sì ní àǹfààní Gẹ̀ẹ́ṣì ní láti má gbé, tí wọ́n ó sì má siṣẹ́ ní EU bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀

Bákan náà ni yóó sì ṣe rí fún ọmọ EU kankan tó bá fẹ́ láti ma ṣiṣẹ́ tàbi gbé ní UK

5. Owó ìfẹ̀yìntì

Àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì tó ń gbé ní EU yóó sì máa gba owó ìfèyìntì wọn lọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yóó ma gba àwọn àjẹmọ́nú tó bá ń gun orí rẹ̀ lọ́dọọdún

6. Dídáwó sí ìsúna EU

Títí ti wọ́n yóò fi pari ètò ìsípò pàda, Uk yóò sì má dá owó sí àpò ìṣúná EU. Ìtumọ̀ èyí ni pé àdéhùn tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ láti máa dáwó sí ètò kan tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ ò ní yẹ̀.

7. Òwò ṣíṣe
Ìdókoòwò UK àti EU yóó sì wà bó ṣe wà láì ní àfikun àwọn owó kankan nínú

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo