Home / Àṣà Oòduà / Ọbásanjọ́ tìkẹ̀kùn mọ́ àwọn òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ níbi òkú àna rẹ̀

Ọbásanjọ́ tìkẹ̀kùn mọ́ àwọn òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ níbi òkú àna rẹ̀

Ọbásanjọ́ tìkẹ̀kùn mọ́ àwọn òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ níbi òkú àna rẹ̀

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní, bí ìṣẹ̀lẹ̀ bá sẹ̀ ní agboolé, a mọ́ ọ kángun sẹ́nìkan ju ẹnìkan lọ.Ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Àárẹ̀ tẹ́lẹ̀rí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo ti sọ ìdí tí òun fi ti ìlẹ̀kùn ilé ìjọsìn mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ àti ojúlùmọ̀, tó wá sí ibi ayẹyẹ òkú ìyá ìyàwó rẹ̀ ní Ọjọ́ Ẹtì.

Bàbá Ọbásanjọ́ nínú àtẹ̀jáde tó fi léde sọ wí pé, nítorí àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì ni òun ṣe gbé ìgbésẹ̀ náà.

Ọbásanjọ́ sàlàyé pé, bí ètò ìsìnkú ọ̀hún ṣe bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́wàá Òwúrọ̀ ni ìjọ Saint Peters Anglican Church tó wà ní ọgbà lsara-Remo, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ni òun fúnra òun ti ìlẹ̀kùn ilé ìjọsìn ọ̀hún, kí àwọn ènìyàn má baà ráyè wọlé.

Ó fikún-un pé òun tẹ̀lé àṣẹ ìjọba tó tako ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn ọlọ́gọ̀ọ̀rọ̀ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kofi-19 yìí.

Níṣe ni àwọn òṣìṣẹ́ àti ojúlùmọ̀ náà dúró síta lẹ́yìn ìgbésẹ̀ Bàbá Ọbásanjọ́, tí wọ́n sì lọ sin òkú ọ̀hún lẹ́yìn ìsìn.

Ó kù díẹ̀ kí Màmá Florence Adenekan pé ẹni àádọ̀rún ọdún ló jáde láyé.

Mama Adenekan ni ìyá Bola Ọbásanjọ́ tó jẹ́ ọ̀kan lára ìyàwó Bàbá Ọbásanjọ́.

Ìròyìn gbé e pé ó wà ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì lásìkò ìsìnkú ìyá rẹ̀, tí Bàbá Ọbásanjọ́ sì ṣe ojú rẹ̀ ní ibi ìsìnkú ọ̀hún.

Lẹ́yìn ìsìnkú náà ni Bàbá Ọbásanjọ́ wá tẹ̀síwájú lọ kí àwọn lọ́balọ́ba tó wà ní agbègbè náà.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...