Home / Àṣà Oòduà / Ogulutu: Olaju ti so ogbon aye atijo di omugo patapata

Ogulutu: Olaju ti so ogbon aye atijo di omugo patapata

#Ogulutu

Ogulutu
Nigba ti mo wa ni kekere, awon egbon adugbo kan wa, awon ti awon obi wa gba wi pe won nimo ju wa lo.

Ti o ba ti n to akoko fun awon egbon ti wa lati wo ile iwe giga, awon obi wa maa n taari won lo ba awon egbon adugbo yii fun itosona nipa orisii eko imo to dara ju lo ni ile eko giga, awon eko to le tete mu eniyan rise tabi di eniyan pataki nikete ti won ba kawe gboye.

Lopo igba, lara awon eko ti awon egbon adugbo naa maa n ka sile ni Imo Isegun, Imo Ajosepo Awon Ilu Okeere, Imo Ero, Imo Ofin, ati bee bee lo.

Bi o tile je wi pe ko si oun to buru ninu kiko awon imo yii ni ile eko giga, sugbon ero okan won eleyii to bi orisii ogbon ti won lo nigba naa ni asise nla.

Ko si imo eko kan ti a ya soto lati mu eniyan di eniyan pataki tabi rise kiakia ju awon yoku lo. Awon ogbon bayii tile le maa sise nigba oju dudu.

Sugbon laye ode oni, ti olaju ti de, iru ogbon bee ti di omugo. Bakan naa ni ko si imo kan to kere tabi ti ko ni iwulo tie fun awujo.

Imo Eko Ede Yoruba ati Litiraso ni mo se ni ile iwe giga lati gboye akoko. Nigba ti awa nile iwe, opo awon akekoo ma n foju wo wa bi igba ti a n fi asiko wa sofo lasan. Nitori wi pe ninu okan won, won maa ro wi pe kini eniyan le fi imo ede Yoruba se.

Yato si ede Yoruba, awon imo eko kan wa ti won tun foju kere won.

Opolopo ireti awon eniyan ti n jabo leyinoreyin, nitori ibi ti won foju si ona o gba be mo.

Pupo inu awon imo eko to “dara ju” yii ni awon eniyan ti lo ko sugbon ti nnkan ko senuure nigba ti won jade.

Ki n to so nipa ogbon aye ode oni to se koko, e je n so die nipa idi pataki ti a fi da eko kiko sile. Ilu Spartan ati Athens ni mooko-mooka ti gbe bere ni Senturi karun-un eleyii ti Pluto je okan lara awon agbateru igbese naa.

Idi pataki ti won fi se idasile eko ni fun ironilagbara eniyan lati le daduro tabi lati le se ohun ti won fe lai se wi pe won duro de iranlowo enikeni.

Sugbon laye ode oni, opolopo gba wi pe pataki eko ni lati ri ise se ati lati je eniyan atata lawujo eleyii to jina si otito.

Bi eniyan ba fe pegede laye ode oni dandan ni ko ko ogbon aye ode oni to le mu ni leke. Nje ogbon wo ni ogbon igbalode abi aye ode oni to le mu eniyan leke? E pade mi lose to n bo.”

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo