Home / Àṣà Oòduà / Olè yabo báńkì: O fowó náà so̩dún Kérésì fáwọn èrò

Olè yabo báńkì: O fowó náà so̩dún Kérésì fáwọn èrò

Olè yabo báńkì. O fowó náà so̩dún Kérésì fáwọn èrò

Bí ayé bá ń lọ sópin, àràǹbarà ìran lojú yóó máa rí. À bí kín ní ká tí pèyí sí pẹ̀lú bí arákùnrin òyìnbó onírungbọ̀ kan ṣe dédé yabo ilé ìfowópamọ́sí kan ní Colorado Springs ní orílẹ̀èdè-ede America jíwó o báńkì.

Kété tó wọlé ló jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ báńkì náà mọ̀ pé olè ni òun àti pé kí àwọn oníbàárà má bẹ̀rù.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ náà ni àwọn òṣìṣẹ́ báńkì kò wulẹ̀ janpata mọ́ nítorí ẹ̀mí wọn tí arákùnrin náà sì ráàyè kó owó tó pọ̀ bó ṣe wùú.
ojú mi tó tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn ní bó ṣe kó owó tán ló rìn jáde síta báńkì náà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fọ́n owó náà ká.

Wọ́n ní bó ṣe ń fọ́n owó náà fáwọn èrò tó ń kọjá lọ níta báńkì ló ń pariwo ” Merry Christmas”

Àwọn agbófinró ṣàlàyé pé ọkùnrin àgbàlagbà náà jalè owó yìí ní Academy Bank tó wà ní Colorado Springs lásìkò oúnjẹ ọ̀sán ni.

Dion Pascale, ọ̀kan lára àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ sọ fún akọ̀ròyìn 11 News tó wà ní Colorado pé ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún gbogbo èrò ojú pópó bí ọkùnrin náà ṣe ń kó owó jáde láti inú báàgì owó tó sì ń fón won dà síta.

Ìròyìn ní kété tí arákùnrin yí fọ́n owó náà ká tàn ló wọ inú Starbucks tí wọ́n ti ń ta àwọn ohun mímu tútù bíi tíì àti kọfí lọ.
Àwọn ó ṣojú ù mi ní bó ṣe wọ inú starbucks tán ló jókòó tó ń retí àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n á tó wá mú òun.

Ìròyìn ní àwọn èrò ojú títì fi ara balẹ̀ ṣa owó náà tí oníkálùkù kò sì kàá sí ẹ̀bùn ọdún kérésì,bi ọkùnrin náà se kéde fúnwọn ṣùgbọ́n tí wọ́n dáa padà sínú ilé ìfowópamọ́sí náà tí ọkùnrin ọ̀ún ti kóo bọ́ síta tẹ́lẹ̀.

Àwọn agbófinró Colorado Springs pe orúkọ ọkùnrin náà ní David Wayne Oliver.

Wọ́n ní ọmọ ọdún márùndíláàdọrin ni àti pé kò dàbí ẹni pé ó ní olùrànlọ́wọ́ kankan tí wọ́n jọ jalè náà rárá.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...