Home / Àṣà Oòduà / Ọ̀ọni ilé ifẹ̀ bẹ̀rẹ̀ fínfín ìtagbangba ní Ifẹ̀

Ọ̀ọni ilé ifẹ̀ bẹ̀rẹ̀ fínfín ìtagbangba ní Ifẹ̀

Ọọ̀nirìṣà ilé Ifẹ, jìngbìnì bí àtẹ àkún,Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ogunwusi bẹ̀rẹ̀ fínfín àwọn ìta gbangba gbogbo ní ìlú Ilé Ifẹ̀ lẹ́yìn tó kéde ríra àwọn ohun èlò afínko láti dẹ́kun ọwọ́jà àrùn apinni léèmí COVID-19.

Ọba Adéyẹyè ra àwọn irinṣẹ́ afínko tí wọ́n ṣe lábẹ́lẹ́ tí owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ náírà láti ṣe ìrànwọ́ fún ìgbésẹ̀ Ìjọba lórí wíwa wọ́ àrùn apinni léèmí Coronavirus bọlẹ̀.

Kábíyèysí Ọọ̀nirìṣà kò ṣàì tẹnumọ́ pàtàkì fínfín àwọn ìta gbangba gbogbo káàkiri ìlú, ìpínlẹ̀ àti jákèjádò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo