Home / Atunyẹwo / Ó Pọ́dún Mẹ́ta Lónìí Tí Aláàfin Adéyẹmí Re Barà.
ALÁÀFIN
Aláàfin Àtàndá Ọláyíwọlá ọmọ Adéyẹmí

Ó Pọ́dún Mẹ́ta Lónìí Tí Aláàfin Adéyẹmí Re Barà.

Kò sẹ́ni tí ó ju sáyé, gbogbo wa la ó dìtàn. Aláàfin Àtàndá ti kópa ti wọn, wọ́n ti lọ. Ọdún kẹta rèé tí Aláàfin Ọláyíwọlá ọmọ Adéyẹmí yíjú kúrò níhìn-ín, Ọláyíwọlá kọjú sáwọn aláṣekù, Baba bá wọn lọ. Iṣẹ́ tí wọ́n ṣe é lẹ̀ là ń sọ, tó dìròyìn. Bí a ti ń sọ ọ̀rọ̀ nípa Ọmọ Ìbírònkẹ́ lónìí, àsìkò ń bọ̀ tí àwọn kan náà ó sọ nípa tiwa. Kí layé á sọ nípa tèmi-tìrẹ?

Ìlẹ̀pa dòdò kó dẹlẹ̀ fún Aláàfin Adéyẹmí, kọ́wọ́ ìbàjẹ́ ó sì má ba gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ 🙏

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...