Home / Àṣà Oòduà / Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú ṣẹlẹ̀ nítorí àṣìṣe àti irọ́ tí China pa lórí coronavirus- Donald Trump

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú ṣẹlẹ̀ nítorí àṣìṣe àti irọ́ tí China pa lórí coronavirus- Donald Trump

Ààrẹ Donald Trump ń tú bí ejò ní o , pé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti sọnù látàrí pé China sahun òótọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ tí àlejò ọ̀ran náà tí fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣé bùba , kó tó wá di àǹkóò tí gbogbo àgbáyé n bọ.

Donald Trump tó ń tukọ̀ Ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti kéde pé àsìse orílẹ̀-èdè China ló pa ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ọ̀rọ̀ àrùn apinni léèmí coronavirus.

Ó ní àjọ elétò ìlera lágbàáyé náà kò pariwo àrùn apinni léèmí COVID 19 bí ó ṣe yẹ tó nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ní China. tó fi di àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé báyìí.

Trump ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfitónilétí tó jẹ́ irọ́ àti èyí tí kò kún tó ni àjọ WHO kọkọ fi síta lórí àrùn apinni léèmí coronavirus tó bẹ sílẹ̀ ní China, l’éyì tó wá di wàhálà fún gbogbo àgbáyé báyìí, tí kóówá n ṣá kíjo kíjo.

Ṣaájú ni Donald Trump ti kọ́kọ́ gbóríyìn fún ilẹ̀ China lórí bí wọ́n ṣe ṣe nígbà tí orílẹ̀-èdè méjéèjì jọ tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn lórí okòwò tuntun.

Trump ní ká sọ pé Àjọ WHO tí tètè gbéra lọ sí Chian tí wọ́n sì ń fi í tó gbogbo agbaye létí bó ṣe yẹ lórí ọ̀rọ̀ àrùn yìí ni, ó ṣeéṣe kí ó má gbilẹ̀ tó báyìí l’ágbàáyé.

O ní aṣiṣe àwọn méjéèjì yìí ló mú ẹ̀mí ọ̀pọ̀ lọ nílọ̀ọ́po ìlọ́po yìí.

About ayangalu

x

Check Also

seun kuti

Orí kó Seun Kuti yọ kúrò lọ́wọ́ ikú ní yàrá ìgbàlejò US

Mary Fágbohùn Olórin Afrobeat Seun Kuti ti fi ìrírí ibanuje ọkàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà han nígbà tí ọta ibọn kan gúnlẹ̀ lójú fèrèsé yàrá igbalejo rẹ̀. O salaye ibapade to ba ni lẹru naa lori oju-iwe Instagram rẹ, o fi fidio ferese ti ọta ibọn naa bajẹ ati iho re han. Seun, ẹni ti o ṣalaye iyalẹnu, beere iwoye ti aabo ni Amẹrika. Ninu fonran naa, Seun Kuti sọ pe oun wa ninu yara igbalejo, ti oun n sinmi, ...