Home / Àṣà Oòduà / Ronaldinho Ń Kó̩ Is̩é̩ Gbé̩nàgbe̩nà Nínú È̩wò̩n Ní Orílèèdè Paraguay

Ronaldinho Ń Kó̩ Is̩é̩ Gbé̩nàgbe̩nà Nínú È̩wò̩n Ní Orílèèdè Paraguay

Ronaldinho ń kó̩ is̩é̩ gbé̩nàgbe̩nà nínú è̩wò̩n ní orílèèdè Paraguay

Lati owo Akinwale Taophic

Ogbontarigi ninu boolu alafesegba to je omo bibi orileede Brazil ti o si ti fi igbakan ri je eni akoko ninu boolu alafesegba kaakiri agbaye, Ronaldinho, ti wa ninu Ewon ni orileede Paraguay bayii lati nnkan bi osu kan seyin latari esun wi pe o lo iwe irinna ayederu wo orileede naa pelu aburo re kan.

Lati igba naa, gbogbo awijare oun ati aburo lori ejo naa, eyin eti adajo ni o n bo si titi di akoko yi, inu ewon ni o wa ti o ti n lo Daola pelu aburo re. Iroyin fi to wa leti wi pe gbogbo awon elewon ni won ni ife re gidi gan-an, ti oun naa si n se daradara pelu won ati wi pe o n ba won gba boolu papo loore-koore lai fi ibanuje okan re han sita rara.

Ni bayii, iroyin tuntun ti a gbo ni wi pe o ti n ko ise gbena-gbena (Capentary works) ninu ewon, ti o si gba oju mo gidi gan an ni.

Ohun ti o tun je edun okan ni wi pe arakunrin yi ti se gudugudu meje ati yaaya mefa ninu boolu alafesegba kaakiri agbaye ajaaja fun orileede abinibi re-Brazil, ohun ti o le fa bi won se wa n wo niran ni ko ye enikankan di akoko yi ati wipe ojo abameta ti o koja lo yi arakunrin naa pe omo ogoji odun laye eyi ti o ba ninu ogba ewon.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo