Home / Àṣà Oòduà / Abiola Ajimobi sùn un re

Abiola Ajimobi sùn un re

Ikú pàgbẹ̀ àṣírí aláró tú.
Ikú pàlùkò àbùkù kará ìkosùn.
Ọrùn má kánjú, gbogbo wa la dágbádá ikú.
Ìgbà átàsìkò ẹ̀dá ló só kùnkùn.
Gíńgín ladáhunṣe tó mewé e re.
Gbogbo wa lòpè nípa àkúnlẹ̀yàn.
Òkú ń sunkú òkú, akáṣọlérí ń sunkú ara a wọn.
Sùn un re oo Àjànàkú ọkọ Florence, Àkànjí ẹ̀rù , mọ́ ṣẹ̀rù baya, bọmọ tó o fi sáyé lọ.
Má ṣẹ̀rù bàlú, sun- un-run ìgbẹ̀yìn pàdé Allah nídẹ̀ra .

Àkànjí ẹ̀rù Sheeeeuuu,ibi o fàdàgbá ayé rọ̀ sí, ọmọ ni yóó lòyókú.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo