Home / Àṣà Oòduà / È̩yin òsìsé̩ mi nílò àyè̩wò coronavirus kíákíá- Akeredolu

È̩yin òsìsé̩ mi nílò àyè̩wò coronavirus kíákíá- Akeredolu

È̩yin òsìsé̩ mi nílò àyè̩wò coronavirus kíákíá – Akeredolu

Arakunrin Rotimi Akeredolu ti o je gomina ipinle Ondo lo n gba awon alabasise re niyanju ki won fi oro ti oun se arikogbon.


O ni iba lasan ni o se oun ti oun si se itoju ara laarin ojo meji pere. O ni leyin re ni awon ore gba oun nimoran lati se ayewo ajakale arun coronavirus.


Gomina naa ni “iyan jija lo n ba ore je” oun se ayewo ti esi ayewo si gbe pe oun ti ko arun naa.


O ni tii di asiko yii, oun ko tii le so ibi ti ati ona ti oun gba ko aisan naa. Alagba Akeredolu salaye yii funra re lori afefe pe ki won wo oun pe saka ni ara da.

Oun ko tile ni inira kankan ni eyi ti awon onimo oyinbo ni ohun lo dara ju. Won ni ti eniyan ba tete kefin arun yii ti o si tete gbogun tii lo dara ju ki o to wo ara.


Eyi lo mu ki gomina gba awon osise re niyanju pe ki won tete lo se ayewo ara won nipa arun naa ki eni to ba nii le tete gbogun tii.

Yínká Àlàbí

About ayangalu

x

Check Also

tirela

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa Fẹ́mi Akínṣọlá Aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ló ń lọ lu lọjọ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kerin 2025, tírélà kan fi jábọ́ láti orí afárá Pen Cinema, Agege, l’Ekoo, tó sì run ọkọ̀ Kórópe méjì tó jábọ́ lé lórí pa. Ajọ Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Atẹjade kan ti Adari iṣẹlẹ bi eyi ati ilaniloye ni LASTMA, Adebayo Taofiq, fi ...