Home / Àṣà Oòduà / Ènìyàn 148 míràn lárùn Covid-19 ní Nàìjíríà–Àjọ NCDC

Ènìyàn 148 míràn lárùn Covid-19 ní Nàìjíríà–Àjọ NCDC

Ènìyàn 148 míràn lárùn Covid-19 ní Nàìjíríà–Àjọ NCDC

Ó ti pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti márùndínládọ́jọ èèyan tó ti ní àrùn apinni léèmí yìí ní Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Èkó ló ṣì ń léwájú.
Ní bí a ṣe ń kó ìròyìn yìí jọ. Iye àwọn tí àyẹwò ti fihàn pé wọ́n lárùn apinni léèmí coronavirus lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó dín àádọ́ta èèyàn báyìí.

Àjọ NCDC ló ṣàlàyé ẹ̀kúnrẹ́tẹ́ èyí nínú ìkéde alálàálẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe láti sọ ibi tí iṣẹ́ dé dúró lórí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kofi 19 lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìpínlẹ̀ Èkó ló ń léwájú lókè téńté àtẹ. Àwọn onímọ ètò ìlera kò sawun òótọ́ ọ̀rọ̀ náà pé, ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé nítorí pé ìpínlẹ̀ Èkó ni ètò àyẹ̀wò rẹ̀ pọ̀jù lọ, ló fa èyí, bákan náà ni Ìpínlẹ Kano náà ti gòkè tẹ̀le pẹ̀lú ìbẹ̀rẹ̀ ètò àyẹ̀wò níbẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye tó wọ tọ ikú ọ̀wọọwọ̀ọ́ àti àìsí ìtọ́jú àti amójútó tó péye fún àjàkálẹ̀ àrùn ajániláyà pàtì méèmí ẹni lọ ọ̀hún tó mú ibùdó síbẹ̀ .

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.