Home / Àṣà Oòduà / Ilé-ẹjọ́ Tó Ga Jù Ní Samuel Ortom Náà Ló Tún Jáwé Olúborí Ní Benue

Ilé-ẹjọ́ Tó Ga Jù Ní Samuel Ortom Náà Ló Tún Jáwé Olúborí Ní Benue

Ilé-ẹjọ́ tó ga jù ní Samuel Ortom náà ló tún jáwé olúborí ní Benue
Láti ọwọ Yínká Àlàbí


Iroyin yajoyajo to wole bayii lo n jeri sii bi ile ejo to ga ju lo to fi ikale si ilu Abuja se da ejo oludije fun ipo gomina ni ipinle Benue, iyen Emmanuel Jime ti egbe oselu APC nu bi omi isanwo.


Awon adajo meje ti Adajo Olabode Rhodes-vivour je olori fun ni won se idajo naa ni nnkan bii ogbon iseju seyin.
Ile ejo ni gbogbo awijare egbe oselu APC ko lese nile, nipa idi eyi ki gomina Ortom ti egbe oselu PDP si maa se ijoba re lo ni alaafia.


Ti a ko ba gbagbe, ana ode yii naa ni ile ejo yii da ejo awon gomina merin nigba ti ti ipinle Imo waye ni ose to koja bi o tile je pe iwode si n lo kaakiri nipa idajo naa.
Awon ti ko te lorun n se iwode bee si ni awon ti ejo naa gbe n se idunnu kiri ilu.

About ayangalu

x

Check Also

ÌKéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ ÌJẹ̀ṣà

Ìkéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà

Ní ìtẹ̀síwájú orò ìwúyè Ọwá Obòkun Àdìmúlà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá Clement Adésuyì Haastrup, wọ́n ti kéde ìṣéde jákèjádò ìlú Iléṣà. Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Àgbà Ọlálékan Fọ́lọ́runṣọ́ tí wọ́n jẹ́ Loro ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ṣe kéde, ìṣéde náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ alẹ́ òní Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ kọkànlá títí di aago mẹ́fà Òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin (8pm of April 11 to 6am of April 12, 2025) Kí eku ilé ó gbọ́, kó sọ fún toko o!!! Gbogbo ènìyàn ...