Home / Àṣà Oòduà / Obirin kan bi omo sinu Keke Maruwa

Obirin kan bi omo sinu Keke Maruwa

Onise ara ni Olorun oba. Omobirin alaboyun kan lo bere si ni robi ninu Keke Maruwa ni akoko ti won gbe lo si ile iwosan lati lo bimo niluu Enugun.  Eyi to ju ibe ni wi pe, ojo odun lo tun wa bosi(1/1/16))nirole patapata. Awon osise ile iwosan alabode ti won fe gbe lo gan-an ti lo sile odun. Sugbon lona ara ati iyanu, obirin adelebo kan ti n koja lo sun mo alaboyun naa nigba ti oko re n keboosi “E gba mi o. Taani yoo ran mi lowo” bonu.

Omobirin adelebo naa tu eru omo ti alaboyun naa gbe dani, o mu awon nnkan eroja jade, o si gbebi omo naa ninu Keke Maruwa ti won fi n gbe lo si osibitu. Olorun fun obirin adelebo naa se to bee gee to je wi pe irorun ni gbogbo re jasi.  Omo wa laye, iya wa laye gbogbo won pata ni won sodun idunnu nidile won.
Keke Maruwa

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...