Home / Àṣà Oòduà / Ò̩pò̩ dúkìá sègbé sínú ìjàm̀bá iná ló̩jà Amu l’Ekoo

Ò̩pò̩ dúkìá sègbé sínú ìjàm̀bá iná ló̩jà Amu l’Ekoo

Ò̩pò̩ dúkìá sègbé sínú ìjàm̀bá iná ló̩jà Amu l’Ekoo
Láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí
Eledua jowo maa so wa pelu ijamba ina to n sele lasiko eerun yii.
Lojiji ni ijamba tun be yo ni oja gbaju-gbaja Amu ti o wa ni ilu Mushin ni ipinle Eko.


Oja yii ni won ti n ta awon igi ikole,abesitoosi ikole ati awon ohun ikole miiran gbogbo.


Awon eso panpana tete de ibi isele yii sugbon epa ko boro ni oro ina naa. Gbogbo bi won se n da omi sii lo n da bii igba ti won da epo petiro si ina naa.
Dukia to le ni bilionu naira lo sofo sinu isele buruku naa, eni to kan lo mo.
Isele yii ba opo eniyan lokan je nitori pe ko si eni ton le mo oja yii tele to maa gbo pe ina joo guruguru ti ko ni kawo mori.
Ko tii si eda Olorun kan to le so ohun to fa ijamba ina naa nitori pe awon onise monamona ko muna wa ni gbogbo asiko naa.
Ki Eledua ba wa dawo aburu duro.

About ayangalu

x

Check Also

ÌKéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ ÌJẹ̀ṣà

Ìkéde ní Yàjóyàjó láti Ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà

Ní ìtẹ̀síwájú orò ìwúyè Ọwá Obòkun Àdìmúlà ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà, Ọwá Clement Adésuyì Haastrup, wọ́n ti kéde ìṣéde jákèjádò ìlú Iléṣà. Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Àgbà Ọlálékan Fọ́lọ́runṣọ́ tí wọ́n jẹ́ Loro ilẹ̀ Ìjẹ̀ṣà ṣe kéde, ìṣéde náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́jọ alẹ́ òní Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ kọkànlá títí di aago mẹ́fà Òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin (8pm of April 11 to 6am of April 12, 2025) Kí eku ilé ó gbọ́, kó sọ fún toko o!!! Gbogbo ènìyàn ...