Ẹ jẹ́ kí á jọ kí GBajúmọ̀ Akọrin Jùjú nílẹ̀ yìí, Olóyè Ebenezer Obey Fabiyi kú ayẹyẹ oríkádún wọn ti ọdún kẹtàlélọ́gọ́rin (83) tó kò lónìí. Kí Olódùmarè ó fi àlàáfíà ṣe ẹ̀bùn Ogbó fún Bàbá

Kò sẹ́ni tí ó ju sáyé, gbogbo wa la ó dìtàn. Aláàfin Àtàndá ti kópa ti wọn, wọ́n ti lọ. Ọdún kẹta rèé tí Aláàfin Ọláyíwọlá ọmọ Adéyẹmí yíjú kúrò níhìn-ín, Ọláyíwọlá kọjú sáwọn aláṣekù, Baba bá wọn lọ. Iṣẹ́ tí wọ́n ṣe é lẹ̀ là ń sọ, tó dìròyìn. Bí a ti ń sọ ọ̀rọ̀ nípa Ọmọ Ìbírònkẹ́ lónìí, àsìkò ń bọ̀ tí àwọn kan náà ó sọ nípa tiwa. Kí layé á sọ nípa tèmi-tìrẹ? Ìlẹ̀pa dòdò kó ...