Home / Iroyin Pajawiri / Ọlọ́pàá ò lè dáwa lọ́wọ́kọ́ àti sèwọ́de àyájọ́ EndSARS, -Oduala

Ọlọ́pàá ò lè dáwa lọ́wọ́kọ́ àti sèwọ́de àyájọ́ EndSARS, -Oduala

Ọlọ́pàá ò lè dáwa lọ́wọ́kọ́ àti sèwọ́de àyájọ́ EndSARS, -Oduala

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọ̀kan nínú àwọn tó ṣagbátẹrù ìwọ́de ta ko àwọn ọlọ́pàá SARS t’íjọba ti fòfin dè, Bọlatito Oduala, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Savvy Rinu ti sọ pé kò s’óhun tó lè dá àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kọ láti má ṣèwọ́de lógúnjọ́ , oṣù Kẹwàá yìí, ní ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ EndSARS tó wáyé lọ́dún tó kọjá.

Oduala sọrọ yii lori ikanni ayelujara rẹ lati fesi si ikilọ tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe ninu atẹjade ti wọn fi lede lọjọ Aje yii, pe awọn o ni i faaye gba iwọde kankan ni iranti iṣẹlẹ EndSARS.

Atẹjade ọhun, eyi ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, buwọ lu sọ pe ipo ẹlẹgẹ ni eto aabo ipinlẹ Eko wa, bẹẹ lo si ri kaakiri orileede yii, tori naa awọn ko ni i faaye gba ẹnikẹni tabi awọn ọdọ lati gun le iwọde eyikeyii lọjọ ayajọ EndSARS, o ni irufẹ iwọde bẹẹ le di eyi tawọn janduku atawọn ajinigbe le darapọ mọ lati dana ijangbọn tabi ki wọn wu awọn araalu lewu.

Odumosu ni gbogbo ilana ati igbesẹ to bofinmu, to wa nikaawọ awọn agbofinro lawọn yoo gbe lati gbegi dina iwọde tabi ifẹhonuhan lọjọ naa, bẹẹ lo si kilọ fawọn obi lati ba awọn ọmọ wọn sọrọ nibi ti wọn ti maa n gbọran.

Ṣugbọn Oduala sọ ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara rẹ ọhun pe ko si nnkan ija tawọn ọlọpaa le lo ti yoo di awọn lọwọ lati ṣewọde lọjọ naa, tori ẹtọ awọn ọdọ ni, awọn si ti ṣeto bo ṣe yẹ.

O lawọn o ni lati gba iyọnda lọwọ ileeṣe ọlọpaa ki iwọde too waye, bẹẹ ni ki i ṣe ojuṣe kọmiṣanna lati kọkọ fọwọ si i tabi tako o.

Savvy Rinu kọ ọ sibẹ pe: “CP Hakeem Odumosu, o o laṣẹ lori ọrọ yii, bẹẹ lo o lẹtọọ kankan lati kilọ, tabi gbegi dina fun awọn to fẹẹ ṣe iwọde alaafia. Oṣiṣẹ ijọba ni o, ojuṣe rẹ si ni lati pese aabo, ko o si daabo bo ẹtọ awọn to maa ṣe iwọde.”

Oduala ni awọn o ni i wọgi le iwọde naa, dandan ni ko waye bawọn ṣe ṣeto rẹ.

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

tirela

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa Fẹ́mi Akínṣọlá Aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ló ń lọ lu lọjọ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kerin 2025, tírélà kan fi jábọ́ láti orí afárá Pen Cinema, Agege, l’Ekoo, tó sì run ọkọ̀ Kórópe méjì tó jábọ́ lé lórí pa. Ajọ Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Atẹjade kan ti Adari iṣẹlẹ bi eyi ati ilaniloye ni LASTMA, Adebayo Taofiq, fi ...