Home / Àṣà Oòduà / Ògún Majek wọ káà ilẹ̀ sùn

Ògún Majek wọ káà ilẹ̀ sùn

Ògún Majek wọ káà ilẹ̀ sùn

Ọlọ́jọ́ ń kajọ́, ẹ̀dá ò fiyè si.
Ìjọ ọmọ tuntun dáyé, nijọ́ ìdùnnú, ẹ̀rín, òhun ọ̀yàyà fún ẹbí,ará, pẹ̀lú ìyekan. Ṣùgbọ́n kìí rọgbọ ká sàdédé sàfẹ̀kù èèyàn ẹni pékú yọwọ́ ọ rẹ̀ ní dúníyàn.

Àsamọ̀ yìí ló díá fún ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ báyìí pé, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà Gbọ́lágadé Akínpẹ̀lú, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ogun Majek ti jáde láyé, bákan náà wọ́n ti sin-ín ní ìlànà mùsùlùmí.

Ọ̀rẹ́ tímọ́timọ́ Ògún Majek tí wọ́n tún jọ jẹ́ òṣèré tíátà, Musiliu Dásọfúnjó, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Èṣù làálú, ló fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún akọròyìn.

Dásọfúnjó ní ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún òun nígbà tí òun gbọ́ nípa ikú ọ̀rẹ́ òun yìí, nítorí kò dàgbà débi tó yẹ kó kú lásìkò yìí.

Dásọfúnjó ní wọ́n gbé Májẹ́kódùnmí dìgbàdìgbà lọ sí iléèwòsàn UCH ní Ìbàdàn, nígbà tí àìsàn rẹ̀ fẹ́ bọ́wọ́ s’órí àmọ́ ẹ̀pa kò bóró mọ́.

Ó fikún-un pé, kìí ṣe pé àgbà ló dé sí ọ̀rẹ́ òun nítorí ọjọ́ orí rẹ̀ kò tíì tó nǹkan, àmọ́ àsìkò ti tó, ni Majek fi di èrò ọ̀run.

Àìsàn kídìnrín àti àìsàn ìtọ ṣúgà ni Majek ti ń bá fínra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kó tó jáde láyé.

Dásọfúnjó fikún-un pé, ọ̀sán òní ni wọn sin Majek gẹ́gẹ́ bí ìlànà ẹ̀sìn mùsùlùmí.

Ọ̀rẹ́ tímọ́timọ́ Ògún Majek, Musiliu Dásọfúnjó ní ìlú wọn ní agbègbè Elesude, lọ́nà Ọmí ní ìlú Ìbàdàn ni wọ́n sin-ín sí.

Musiliu Dásọfúnjó ní àwọn ẹgbẹ́ òṣèré Yorùbá ló se kòkàárí ètò ìsìnkú rẹ̀.

Ọ̀rẹ́ olóògbé náà wá sàpèjúwe Ògún Majek gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní sùúrù, tí kìí sì í fa wàhálà.

“Majek jẹ́ ẹni tí kò sí nǹkan tí kò ba lára mu, tó sì tutù ní ìwà.”

Dásọfúnjó tún ní “láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, Majek jẹ́ ẹni tó lawọ́, tí kò bá ní, ó máa ń jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún un.”

Dásọfúnjó ní ohun tó dun òun jù ni pé, òun kò ní rí i mọ́, tí wọn kò sì ní leè sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìléwọ́ mọ́.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Ọlọ́pàá ò lè dáwa lọ́wọ́kọ́ àti sèwọ́de àyájọ́ EndSARS, -Oduala

Ọlọ́pàá ò lè dáwa lọ́wọ́kọ́ àti sèwọ́de àyájọ́ EndSARS, -Oduala Ọrẹ Òtítọ́jù Ọ̀kan nínú àwọn tó ṣagbátẹrù ìwọ́de ta ko àwọn ọlọ́pàá SARS t’íjọba ti fòfin dè, Bọlatito Oduala, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Savvy Rinu ti sọ pé kò s’óhun tó lè dá àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kọ láti má ṣèwọ́de lógúnjọ́ , oṣù Kẹwàá yìí, ní ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ EndSARS tó wáyé lọ́dún tó kọjá. Oduala sọrọ yii lori ikanni ayelujara rẹ lati fesi si ikilọ tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ...