Home / Àṣà Oòduà / Àlùfá tọ́ bá ọmọ ọdún méje sùn, wẹ̀wọ̀n ọdún Márùn- ún ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Àlùfá tọ́ bá ọmọ ọdún méje sùn, wẹ̀wọ̀n ọdún Márùn- ún ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Ọjọ́ gbogbo n t’olè, ọjọ́ kan n t’olóhun.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tífìtàn balẹ̀ bí wọ́n ṣe jẹ́ ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ láti máa dárúkọ ọ̀daràn afipá bánilòpọ̀ hàn àti láti máa dójú tì wọ́n.

Gómìnà ìpínlẹ̀ náà Kayode Fayemi gbé e jáde lójú òpó twitter rẹ̀ pé àsìkò ti tó láti máa fi ojú aṣebi hàn lásìkò tó gbé àwòrán ẹni ọ̀wọ̀ Asateru Gabriel ti ìjọ St Andrew Anglican Ifinsin -Ekiti nígbà kan.

Gabriel ti fọjú ba ilé ẹjọ ó si jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan, nítori ìdí èyí yóò maa ṣẹ̀wọ̀n ọdún márùn ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Ìjọba ní Ado Ekiti fún ẹ̀sùn ìfipá bá ọmọ ọdún méje lòpọ̀.

Ní bayiì orúkọ rẹ̀ ti wọ ìwé àkọsílẹ̀ àwọn olùfipábánilòpọ̀ ní ilé ìṣẹ́ ìdajọ́.

Èyí jẹ́ ìpínlẹ̀ Gúúsù- ìwọ̀ -oòrùn àkọ́kọ́ tí yóò gbé ìgbesẹ̀ yìí.

Fẹ́mi Akínṣọlá
Iroyinowuro

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo