Home / Àṣà Oòduà / Ó di láyéláyé pọngbá ! Àlàbí Yellow ,àgbà òṣèré re’bi àgbà á rè

Ó di láyéláyé pọngbá ! Àlàbí Yellow ,àgbà òṣèré re’bi àgbà á rè

Ó di láéláé pọngbá ! Àlàbí Yellow ,àgbà òṣèré re’bi àgbà á rè

Gbajúgbajà òṣèré Samuel Akinpẹlu tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Àlàbí Yellow ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá nípè.

Akọni tí à ń perí yìí jẹ́ òṣèré tí àwọn èèyàn kò leè gbàgbé , fún irú ipa tó máa ń kó nínú eré sinimá àgbéléwò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Nígbà tí ó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré,TAMPAN, Bolaji Amusan, Mr Latin fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ tó sì ní àdánù ńlá ni ikú Àlàbí Yellow jẹ́ lágbo òṣèré

Nílé rẹ̀ tó wà ní Ikorodu ni Àlàbí Yellow dákẹ́ sí ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú lẹ́yìn àìsàn tó ti fi ìgbà díẹ̀ dè é mọ́lẹ̀.

Latin ṣàlàyé pé òun ti ní kí Alága ẹgbẹ́ TAMPAN tó wà ní Ikorodu lọ tojú sí mọ̀lẹ́bí olóògbé.

Sinimá tó kópa kẹ́yìn nínú rẹ̀ ni Mọkálíìkì tí Kunle Afolayan darí rẹ̀

Àìlera ti ń bá Àlàbí Yellow fínra fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó wá di pé ó jawàá lẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú.

Fẹ́mi Akínṣọlá

http://iroyinowuro.com.ng/2019/12/23/o-di-layelaye-pongba-alabi-yellow-agba-o%e1%b9%a3ere-rebi-agba-a-re/

About ayangalu

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...