Bómbù déru bà wón ní ilé-ìfowópamó Diamond (Diamond bank) ní ìlú Jos, Bí won se fura wípé wón ti wà okò kan gúnlè tí irinsé olóró Bómbù sì wà ní inú rè. Gbogbo òsìsé ilé-ìfowópamó Diamond ti eka Katako, ní Jos, àti àwon olùgbé ti sí kúrò léyìn tí okò afurasí tí ohun ìjà olóró wà nínú rè wà gúnlè ní iwájú ilé-ìfowópamó náà.
Ilé-isé kan tí a mò sí JTown connect metro kójopò wípé wón ti wa okò náà gúnlè fún ojó kan àti òpò wákàtí séyìn tí enikéni kò sì wá fún un.
Olùgbé àti òsìsé ilé-ìfowópamó ti eka Katako tí èrù ti ń bà pariwo síta or àwon tí ó le gbógun ti Bómbù, won kò sì pé tí won fi dé ibè.
Àwon tí ó ń gbógun ti Bómbù dí ònà tí òpò ènìyàn ń gbà láti dáàbò bo ènìyàn pèlú okò tí ó ń kojá.
Léyìn ìgbà tí won ti se ìwáàdí àti àyèwò fínífíní, àwon olù gbógun ti Bómbù gbógun ti ohun olóró yìí tí ó sì túká yángáyángá. Wo àwòrán síi ní ìsàlè….
English Version
Continue after the page break
Pages: 1 2