Home / Àṣà Oòduà / Odun odun kan ko dun dun

Odun odun kan ko dun dun

Ko dun bi odun yi ri
Odun ti o dun ni odun ominira1960
Odun n dun ni dundun n dun
Orile-ede ti n San fun wara ati oyin
Orile-ede abinibi Nigeria
Adugbo ti n toro
omo ale ni ke ti i dagba
Ki lode ti iku wa di ponkan to o ro
Ti ibon n ro gbamugbamu
Losan-an gangan
Aaro kutukutu kuku ni isele
N la ti n se ti gongo ti n so
Titi di ojoale kerere
Bo ba doganjo
ibon o kan maa yoofin lenu ni
Alarinfesesi yoo si ti fi nnkan gbara
Ohun gbogbo a wa pa kese
Awon alakori bokoharam, Fulani….
Nibi ti iku ti gbe n pe iku ran nise
Loju alusi iji ti n gbe ketepe ogi
Iru itu wo lelekuku elubo le pa
olomokuuya, iku dohun amusere
Ere buruku, eree gele
Ibon wa se pe pe pe
Lara omo eniyan
E e si maa wo tikunle abiamo !
Nigeria nibo la n lo?

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo