Home / Àṣà Oòduà / Àánú àwo̩n tí kò gbàgbó̩ pé covid-19 wà ń se mí – Sanwo-olu
sanwoolu

Àánú àwo̩n tí kò gbàgbó̩ pé covid-19 wà ń se mí – Sanwo-olu

Àánú àwo̩n tí kò gbàgbó̩ pé covid-19 wà ń se mí – Sanwo-olu

Gomina ipinle Eko,Alagba Babajide Sanwo-olu lo n salaye yii fun awon alase ati awon akekoo ile-iwe Corona ni ilu Eko.

O ni o se oun laanu pe bi ijoba ibile,ipinle ati ijoba apapo se n pariwo to lori redio, telifison ati awon iwe iroyin gbogbo. Awon kan si tun ko agidi bole pe ko si oun to n je covid-19.
Gomina ni ti won ko ba tile fe gba ti ile yii gbo, se bi won n gbo tabi ri ti awon orileede agbaye to ku.

O ni awon kan tile ro pe arun olowo ni,gomina salaye pe ko si eni ti ko le mu.
Gomina ni eyi to je ki o maa daru mo awon kan loju ni iroyin awon to loruko ti ajakale arun naa n ba ja ati awon to n pa ti won n gbo. O ni aimoye eni ti ko loruko ni arun naa ti ko lu bee si ni aimoye lo ti ran lo si orun osan gan-an.

Sanwo-olu ni opo ni ko tile de ile iwosan rara ti o je wi pe covid-19 naa lo pa won.
Gomina tun ro awon akekoo pe ki won ni suuru pelu ijoba nitori alafia won lo je ijoba logun. O ni o di igba ti arun yii ba ko ara re kuro nile ki won to le wole eko won. O si gba won niyanju ki won ma se so ireti nu nipa yiye iwe won wo nigba gbogbo. Ori ero ayelujara zoom ni ipade naa ti waye.

Yínkà Àlàbí

About ayangalu

x

Check Also

sanwoolu

Gómìnà Eko, Sanwó-Olú jẹ́jẹ̀ẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn ọlọ́pàá tó lùgbàdi

Gómìnà Eko, Sanwó-Olú jẹ́jẹ̀ẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn ọlọ́pàá tó lùgbàdi Fẹ́mi Akínṣọlá Ṣé wọ́n ní ìgbẹ̀yìn làásìgbò kan kìí bímọ tó rọ̀. Làásìgbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkó láìpẹ́ yìí ti mú kí Gómìnà ìpińlẹ̀ náà, Babájídé Sanwó-Olú ó pàsẹ fáwọn ilé tó ń ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní ìpińlẹ̀ ọ̀hún láti fún ọmọ àwọn ọlọ́pàá tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ abájádè ìfẹ̀hónúhàn ọ̀rọ̀ EndSars rìn. Bákan náà ni Sanwó-Olú tún ní gbogbo ẹbí wọn ni yóò gba owó ìrànwọ́. Gómìnà tún kéde ...