Gómìnà Eko, Sanwó-Olú jẹ́jẹ̀ẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn ọlọ́pàá tó lùgbàdi
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ìgbẹ̀yìn làásìgbò kan kìí bímọ tó rọ̀.
Làásìgbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkó láìpẹ́ yìí ti mú kí Gómìnà ìpińlẹ̀ náà, Babájídé Sanwó-Olú ó pàsẹ fáwọn ilé tó ń ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní ìpińlẹ̀ ọ̀hún láti fún ọmọ àwọn ọlọ́pàá tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ abájádè ìfẹ̀hónúhàn ọ̀rọ̀ EndSars rìn.
Bákan náà ni Sanwó-Olú tún ní gbogbo ẹbí wọn ni yóò gba owó ìrànwọ́.
Gómìnà tún kéde pé, ètò wà nílẹ̀ láti tún gbogbo àwọn àgọ́ ọlọ́pàá tí wọn ti dáná sun, tí wọn yóò sì ra ọkọ̀ míràn tí àwọn jàndùkú ti bàjẹ́.
Babajide ṣe àwọn ìlérí yìí lásìkò tó sàbẹ̀wò sí olú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìlú Ikeja láti báwọn sọ̀rọ̀ ìwúrí.
Àtẹ̀jáde kan fi yéni pé, ó kéré tàn àgọ́ ọlọ́pàá mọ́kàndílọ́gbọ̀n ní wọ́n sùn níná, tí àwọn ibùdó ọlọ́pàá kéékèké mẹ́tàdínlógún sì lọ síi pẹ̀lú.
Ó ní ojúṣe kò ṣe é fọwọ́yẹpẹrẹ mú láwùjọ nítorí ìwà ìbàjẹ́ àwọn kan láàrín ọlọ́pàá, àti pé àìsí ọlọ́pàá láàrín ìlú lẹnú ọjọ́ mẹ́ta jẹ́ ǹkan tí ó kan gbogbo ará ìlú.
“Kọmísọ́nà ọlọ́pàá tí fí ìwé ẹ̀dùn ọlọ́pàá ṣọwọ́ sí ìjọba, àtàwọn ǹkan tí yóò mú ìwúrí bá àwọn ọlọ́pàá lásìkò yìí.
“Lẹ́yìn gbogbo làásìgbò tó wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá. Èmi gẹ́gẹ́ bíi gómìnà mo gba gbogbo ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bi mi, pàápàá jùlọ àwọn ǹkan alò tí kò tó, láti ọjọ́bọ, ọjọ́ kọkàndílọ́gbọ̀n, oṣù kẹwàá, gbogbo àwọn ǹkan tí ó wà nínú ìwé ẹ̀bẹ̀ yìí ni àó máa gbé ìgbésẹ̀ lórí ẹ̀”
” Pàtàkì jùlọ nínú àwọn ìwé ẹ̀bẹ̀ ọlọ́pàá ní fífún àwọn ọmọ ọlọ́pàá tó d’olóògbé ni ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́, mo si ti dári àjọ tó n mójú tó ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ nípìnlẹ̀ Eko láti fún gbogbo àwọn ọmọ wọ́n ni ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí Sanwó-Olú ṣe sọ gbogbo ọlọ́pàá tó bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó yóò ní ètò adójútòfò ẹ̀mí (Life Insurance).
Bákan náà ló fi kún un pé, òun yóò pèsè ẹ̀rọ amúná wá 150kva fún àwọn ọlọpàá àti pé ìjọba yóò sowọ́n pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ mọ̀nàmọ́nà aládàáni, tí wọn yóò fi máa ní iná ní gbogbo ìgbà.
Ẹ̀wẹ́, gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, ọjọgbọ́n Babgana Zulum ṣe ìfílẹlọlẹ̀ ẹbún owó, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààd’ọ́ta naírà fún gbogbo àwọn opó tí ọkọ wọ́n kú nítorí wọ́n farajì láti dáàbò bo ilú (Fijilanté àti àwọn ọdẹ) tí wọ́n sì darapọ̀ mọ́ ọmọogun gẹ́gẹ́ bí ará ìlú.
Bákan náà ni Gómìnà tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ wọ́n