Home / Àṣà Oòduà / Àwọn Fíìmù Òde Òní Ń Kọ́mọ Lólè Àti Ọ̀pọ̀ Ìwà Burúkú – Iyabo Ogunsola

Àwọn Fíìmù Òde Òní Ń Kọ́mọ Lólè Àti Ọ̀pọ̀ Ìwà Burúkú – Iyabo Ogunsola

Àwọn fíìmù òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ẹgbẹ́ burúkú ba ìwà rere jẹ́.

Ajíyìnrere Felicia Iyabode Ogunsola tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Efúnsetán Aníwúrà, Ìyálọ́de ìlú Ìbàdàn nínú eré, ti kìlọ̀ fáwọn òṣèré tíátà láti dẹ́kun àṣà ṣíṣíra sílẹ̀ nínú fíímù.

Efúnsetán ní àṣà burúkú gbáà ni.
Ó ṣàlàyé pé kìí ṣe ohun tó dára kí àṣírí ọyàn máa hàn síta,iṣẹ́ Èṣù ni.

Ó fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá nígbà tí òun fi ń ṣeré lábẹ́ ògbóǹtarìgì òṣèré, olóògbé Iṣhola Ogunsola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Isho Pepper.

Iyabode Ogunsola ní àṣà àìbìkítà, àti àìlójútì gbá à ni.
Ó ní àṣà àwọn òyìnbó ni àwọn òṣèré òde òní ti gbé wọ eré tíátà Yorùbá.

Àgbà òṣèré náà ní àṣà kí á máa yìnbọn pò pò pò nínú fíímù ló kọ́ àwọn ọmọ lólè láyé òde òní, dípò kí àwọn ọmọdé máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀.

Ó rọ ọ̀pọ̀ òṣèré tí wọn kò tíì lọ kẹ́kọ́ọ̀ eré tíátà ṣíṣe níbì kankan pé kí wọ́n yára tètè lọ se bẹ́ẹ̀ nítorí kò sí òṣèré kan tí kò kẹ́kọ́ọ̀ lábẹ́ ẹnìkan nígbà tàwọn náà.

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo