Home / Àṣà Oòduà / E̩ Fi Àdúrà Rànmí Lọ́wọ́, Nítorí Ọmọkùnrin Mi Ti Lùgbàdi Àrùn Coronavirus … Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ Yìí Nígbà Kan

E̩ Fi Àdúrà Rànmí Lọ́wọ́, Nítorí Ọmọkùnrin Mi Ti Lùgbàdi Àrùn Coronavirus … Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ Yìí Nígbà Kan

Ẹ fi àdúrà rànmí lọ́wọ́, nítorí ọmọkùnrin mi ti lùgbàdi àrùn coronavirus … igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ yìí nígbà kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjàkálẹ̀ àrùn kan tí gbogbo àgbáláayé ń kó bẹ́ẹ́rẹ́ fún lásìkò yìí tí kò mojú Ọba tìjòyè mẹ̀kúnù àti olówó ló tí kọlu ọmọ ìgbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ yìí tẹlẹ o .
Olùdíje fún ipò Ààrẹ fẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abuabakar ló fọ̀rọ̀ yìí léde lójú òpó Twitter rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ Àìkú.

Atiku ṣàlàyé pé òun ti sọ fún àjọ tó ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC, àti pé ọmọ náà ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn olùkọ́ni Fásitì Abuja tó wà ní Gwagwalada.

”Inú mi yóó dùn tí ẹ bá le fi ọmọ mi sínú àdúrà yín, kí oníkálùkù rọra máa ṣe nítorí òtítọ́ ni pé àrùn coronavirus wà níta,” Atiku ló sọ bẹ́ẹ̀.

Atiku tún gbóríyìn fáwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn covid-19 yìí.

”Mo rọ gbogbo ọmọ Nàìjíríà pé kí wọ́n má mi kàn tí a ó fi ṣẹ́gun àrùn coronavirus ní Nàìjíríà,” Atiku ló wòye bẹ́ẹ̀.

Ọgbọ̀n èèyàn làjọ NCDC ti kéde pé wọ́n tí ní àrùn afopin sí mímí èémí tí wọ́n ń pé ní coronavirus ní orílẹ̀ yìí, nínú èyí tí àwọn méjì ti rí ìwòsàn.

About ayangalu

One comment

  1. One of my oldest twitter friend omo odua!

x

Check Also

Bàbá mi máa jáwé olúborí ipò Ààre̩ ló̩dún 2023 – Adamu Atiku

Bàbá mi máa jáwé olúborí ipò Ààre̩ ló̩dún 2023 – Adamu Atiku Alhaji Atiku Abubakar ni igbakeji Aare tele ri ni orileede yii. Oun ni igbakeji Oloye Olusegun Obasanjo nigba naa.Atiku dije du ipo Aare ni odun 1993 ni eyi ti o se ipo keta tele M K O Abiola ati Babagana Kingibe labe egbe oselu SDP.O tun dije du ipo Aare ni odun 2007 labe egbe oselu AC sugbon ni igba ti oruko oludije jade, oruko Atiku Abubakar ko ...