Ile-ejo giga to fi ikale si ilu Abuja lo pase fun ijoba apapo pe ki won yokun lorun Ogbeni Omoyele Sowore.
Sowore ni o n gbimo lati se iwode Kan to maa mi ilu titi. Lati igba naa ni ijoba apapo ti fi owo sinkun ofin mu u.
Ogbeni Sowore ti lo ojo marundinlaadota ninu ayanran awon olopaa bayii.
Agbejoro agba to n gbejo fun Sowore, Alagba Femi Falana ni kia ni oun maa ko iwe ti ile-ejo ni ki awon ko ki won le yonda re fun awon ebi re ni oni ojo kerinlelogun, osu kesan-an yii.
Ile-ejo ni ki awon agbofinro gba gbogbo iwe irinna Sowore, ki Alagba Falana si mo daju pe orun oun lo wa. Ile-ejo ni igbakuugba ni awon le pee lati wa jejo.
Main