Home / Àṣà Oòduà / Fayemi, ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) kìí ṣe Kano tí wọn ti ń yọ Emir lórí oyè… Alaafin

Fayemi, ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) kìí ṣe Kano tí wọn ti ń yọ Emir lórí oyè… Alaafin

Àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ojú òpó ìkànsíraẹni Twitter ti dásí ọ̀rọ̀ láàrin Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi àti àwọn ọba ní ìpínlẹ̀ náà.

Èyí kò sẹ́yìn lẹ́tà tó jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti kìlọ̀ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti láti ṣọ́ra ṣe, ki o si tẹlẹ jẹjẹ.

Ìròyìn ohun jáde pé, Gómìnà Fayemi ni wọ́n ló fi ìwé wítẹnuùrẹ ránṣẹ́ sí àwọn ọba mérìndínlógún ní ìpínlẹ̀ nítorí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí òun lẹ́nu.

Fayẹmi ni wọ́n ló sọ pé àwọn ọba náà kọ̀ láti wá si ìpàdé àwọn lọ́balọ́ba àti Ìjọba láti Oṣù Kẹjọ, ọdún 2019 nítorí náà, kí wọ́n sọ ìdí tí wọ́n fi gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Àmọ́ Aláàfin nínú lẹ́tà tí wọ́n ló kọ sí Fayẹmi sọ wí pé, àgbáríjọpọ̀ àwọn ọba ní ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) ló fọwọ́sowọ́pọ̀ fi ìkìlọ̀ náà ránṣẹ́ sí gómìnà náà, láti máṣe fi orí adé tẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ̀.

Aláàfin ní inú àwọn ọba náà kò dùn nítorí pé Gómìnà Fayemi fi ọba tó kéré ní ipò jẹ adarí ẹgbẹ́ àwọn lọ́balọ́ba nípìńlẹ̀ náà, Ìdí sì nìyí tí wọ́n ṣe gbé ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé.

Àmọ́ àwọn ènìyàn to fèsì lórí Twitter sí lẹta náà sọ wí pé, ohun tí Aláàfin ń sọ yìí ló ń kìlọ̀ fún Fayemi wí pé, ilẹ̀ Oòduà (Yorùbá) kìí ṣẹ̀ ìpínlẹ̀ Kano tí gómìnà ti ń yọ Emir, tí yóó sì le kúrò ní ìlú nígbà tó bá wù ú.

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn míràn sọ wí pé, ìbẹ̀rù bojo mú àwọn ará Èkìtì nítorí Fayemi fẹ́ yọ Èwí ti ìlú Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe àti àwọn ọba mọ́kànlá míràn, tó ń fapá jánú sí gómìnà ìpínlẹ̀ náà.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo