Home / Aarin Buzi / Gobe sele lagbo Davido

Gobe sele lagbo Davido

Orisiirisii ara ni awon omo olorin igbalode maa n da lagbo ere orin. Iru ara bee ni bi ki won bo aso lorun ki won si ju si aarin ero onworan. Awon mii a maa bo alakorun danu soju agbo lati fi ife han. Nigba mii ewewe, won maa da bi oti tabi omi inu ike si awon ero ti n je igbaladun won loju agbo ariya.

 

Iru asa yii naa ni Dafidi omo Adeleke ti gbogbo eniyan mo si Davido da lara lagbo ere re kan ni Ilu Burkina Faso. Alase ile ise orin HKN da omi inu ike si ara awon ero onworan nibi o ti n korin. Nibi ti Davido ti n fo soke ti n yo bi eni iya re bimo tuntun ni maanu giripa kan ba jade wa ba a lori pepe laaarin awon ero.

O gba omo baba olowo laso mu girigiri, bee ni i gbo jigijigi, to si n bi leere idi to fi n da omi si oun lara. Opelope awon osise alabo omokunrin olorin naa, ese nla rigidi ti maanu naa gbe soke ko ba sokale sori gongo imu Davido baba Imade nibi o ti n jo Skelewu pelu sokoto re to gbe si bebere-idi.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...