Home / Àṣà Oòduà / Ìdí tí nó̩ḿbà ìdánimò̩ kò fi jé̩ dandan mó̩ – Àjo̩ JAMB

Ìdí tí nó̩ḿbà ìdánimò̩ kò fi jé̩ dandan mó̩ – Àjo̩ JAMB

Ẹ kò nílò nọńbà ìdánimọ̀ NIN fún ìdánwò àṣewọlé ọdún 2020… Àjọ JAMB

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ni báyìí Àjọ tó ń rí sí ìdánwò àṣewọlé ilé ẹ̀kọ́ gíga JAMB tí kó àfàró nípa lílo nọ́mbà ìdánimọ̀ “NIN” fún ìdánwò àṣewọlé ọdún 2020.

Ọ̀gá àgbà àjọ JAMB, Ishaq Oloyede ló fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ l’Abuja.

Bákan náà ni àjọ ọ̀hún fi ọ̀rọ̀ náà léde lójú òpó abẹ́yefò rẹ̀, níbi tó ti darí àwọn olùṣèdánwò láti fi orúkọ wọn ránṣẹ́ sí 55019 fún ìforúkọ sílẹ̀ ìdánwò náà.

Ishaq sọ pé, ìdádúró lílo nọ́ńbà ìdánimọ̀ náà jẹ́ ọ̀nà láti fún àwọn tó ń ṣe ìdánwò JAMB lánfààní síi, láti leè gba nọ́ńbà ìdánimọ̀ wọn.

Ó ní ìgbésẹ̀ náà tún jẹ́ ọ̀nà láti leè wá ojútùú sí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó ń wáyé ní àwọn ojúko ìdánwò JAMB káàkiri orílẹ̀èdè-ede yìí.

Ọ̀gá àgbà ọ̀hún ṣàlàyé síwájú síi pé, àwọn olùṣèdánwò kò nílò nọńbà ìdánimọ̀ fún ìdánwò ọdún 2020, ṣùgbọ́n wọn yóó nílò nọńbà náà fún ìdánwò ọdún 2021.

Ṣaájú lọ́dún 2019 ni àjọ JAMB sọ pé àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìdánwò àṣewọlé ọdún yìí yóó nílò nọńbà ìdánimọ̀ náà láti leè fòpin sí bí àwọn kan ṣe má ń forúkọ sílẹ̀ fún ìdánwò ọ̀hún ju ìgbà kan lọ.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...