Home / Aarin Buzi / Igba wo ni Pasuma fe ni Aya leyin odun mokandilaadota (49)?

Igba wo ni Pasuma fe ni Aya leyin odun mokandilaadota (49)?

Igba wo ni Pasuma fe n’iyawo leyin odun mokandilaadota (49)? Olayemi Olatilewa

Wasiu Alabi Pasuma tun ti pada so fun awon ololufe re wi pe ko ti to asiko fun oun lati ni iyawo nile. Oga Nla fuji, eni ti yoo pe omo odun mokandinlaadota (49) ninu osu kokanlan odun yii, so wi pe oun gbadun igbe aye oun gege bi baba-n-dagbe. Ati wi pe ki enikeni ma ti oun lo sibi ti oun ko ti setan lati lo.

“Awon eniyan n yo mi lenu lori oro iyawo, mi o tile le so iye igba ti mo ti dahun ibeere lori koko oro kan naa. Bi o tile je wi pe o wu mi lati ni aya nile lojo kan, sugbon mo n gbadun igbe aye mi bayii gege bi apon”.

Iba Wasila, eni ti awon kan tun pe ni Popsie Aliyah la gbo wi pe o ti bi omo bi mefa sita. Gege bi iwadii IROYIN OWURO, Ijaya fuji ti fi awon igba kan tami oge si Ayo Adesanya ati Ronke Odusanyani ti won je osere tiata sugbon ti oro won ko pada wo.

Ojo ketadinlogbon osu kokanla, odun 1967 ni won bi Pasuma si Mushin to wa ni Ipinle Eko. Omo ilu Ilorin Afonja ni sugbon Mushin lo dagba si l’Eko oba Akiolu.

Odun 1984 lo bere ise orin, igba to di odun 1993 to gbe awo re akoko jade to pe ni “Recognition.” Ninu awon olorin Fuji, Pasuma je enikan to sun mo awon olorin takasufe ile Naijiria ju lo.

Boya eleyii lo mu oun naa gbe awo orin takasufe re jade lojo keji osu kejo odun 2015 eleyii to pe ni “My World”.

Lara awon olorin to kopa ninu awo orin Pasuma naa ni Olamide, Tiwa Savage, Oritsefemi ati Patoranking.

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*