Home / Àṣà Oòduà / Ijinle Ninu Oro Ifa Fi Ye Wa Nipa Bi Ila Se De Atelewo Wa.

Ijinle Ninu Oro Ifa Fi Ye Wa Nipa Bi Ila Se De Atelewo Wa.

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Ojó oni a san wa o ao ri tiwa se o ase.
Gegebi awon opolopo eniyan se maa nsoro wipe “atewolabala ao meni to ko” lotito la ba ila latelewo wa sugbon imo ijinle ninu oro ifa fi ye wa nipa bi ila se de atelewo wa.
Odu ifa naa ki bayi wipe:
Ogbe karele omo osin
Ogbe karele omo ora
Omo Ogun rere ona alede

 
A difa fun Orunmila baba nsawo nre ona to jin gborogodo bi ojo, seni Orunmila wa gbodo wale agbede orun ro latari irin ajo to nlo bi yio se kere oko bo wale nibe sugbon ako rifa kan meji OGBEKA lodu to hu, oke iponri Orunmila wa sofun wipe obi ” ARILA” ni ki o fi bo oun oke iponri ki o to maa lo, lesekese Orunmila be sita o wa obi arila lo sugbon baba ko ri obi arila yi, bi Orunmila se fi igbagbo nlo si irin ajo re niyen nitoripe o fe bo oke iponri re sugbon kori nkan ti oke iponri gba lowo re, ibiti Orunmila wa ti nlo se lo wa ri igi obi kan to so opolopo eso sori inu Orunmila dun wipe oun ti ri obi arila ti oun yio fi se oke iponri oun Orunmila wo egbe otun o wo egbe osi o paruwo si oloko sugbon kosi eni to dalohun laimo wipe esu odara nbe ninu Igbo nibiti o lubo si, bi Orunmila se gun igi obi niyen to si ja eso kan nibe bi Orunmila se maa so kale seni esu odara jade si Orunmila esu odara ni iwo Orunmila o jale! Oni obi to ja yen oni se oun lo gbin?

 

Orunmila da esu odara loun wipe oun ko jale oni o ti se die ti oun ti nwa arila obi lati fi se oke iponri oun ti oun kori oni nigbati oun si ri igi obi to so yi oun ti pe oloko sugbon oun ko gburo enikookan loun se wa ja eyokan ninu obi naa, esu odara ni Orunmila maa foju kan ile olofin bi esu odara se yo obeke jade niyen to fi fa ila si atelewo Orunmila iyen fun amin idaniloju wipe lotito ni Orunmila jale bi Orunmila se pada sile niyen to si fi obi naa se oke iponri re, nigbati o se oke iponri re tan, oke iponri naa tun sofun wipe ki o lo ni obuko ki o fi ewe ayajo ifa di lenu ki o lo fi esu odara Orunmila si rubo, nigbati o di ojo Keji seni esu odara pe gbogbo ara ilu jo wipe oun mu ole kan lana nibiti o ti nji obi olofin ka oni oun si fi obeke oun fa ila si latelewo fun amin idaniloju nigbati won wa so wipe ki onikaluku maa si atelewo re lesekese ila ti wa ni gbogbo atelewo awon eniyan patapata, eru ba esu odara lo ba nse kamikami kami ko wa mo eni to maa mu jade mo nigbati o je wipe ko si ila latelewo awon eniyan tele ti ila si ti de atelewo won, bi Orunmila ko se gbere itiju niyen laarin awon eniyan o ojo naa ni awon eniyan wa bere sini nwo atelewo ara won kiri, won wa mu esu ni alarekereke, Orunmila wa bere sini njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.

 
Idi niyi to fi je wipe obi arila ni a saba ma fi nbo odu naa, ati wipe ti abafe bo esu nibe oni ewe ayajo ti a gbudo fi di enu obuko ti a fe lo ki a to pa sori esu naa. Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ako ni gbere itiju laye o, gbogbo ibiti a ti lepon de ako ni te nibe laelae asiri wa yio maa bo ni lojo gbogbo esu odara koni fedi wa sita o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

 

ENGLISH VERSION

continue after the page break…

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opónÒla laó sákà lágbèrùKùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòniKáyáa múlé pontíKámú òdèdè rokàKáfi agbada dínranÀwèje wèmu nípón omodé wòyí lójúÒrìsà lópabuké tánLódákún sábaro nídìíOmo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjoOmo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjoIlé-ifón kògba obàtáláÈlàgboro kògba òrìsàOjúgboro ni tàfínÈlàgboro ni tòrìsàOmi níti ojú-omi rúwáÈròyà wáàponÈròyà wáàmuRúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkòErú kùnrin won nííjé bánakúErú bìnrin won nííjé wòrúkúDimúdimù aleìgbòOkùnrin yàkàwú orí ìgbáÌgbá kòwóOkùnrin yàkàwú kòsòkalèÒní laóko igbó olú-kóókó-bojoÒla laóko igbó olú-kóókó-bojoAkogbó olú-kóókó-bojo tánApa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtíWónní kí ...