Home / Àṣà Oòduà / Ìjọba Àpapọ̀ Kò Gbẹ́sẹ̀lẹ̀ Lé Owó Tó Tọ́ Sáwọn Ìjọba Ìbílẹ̀ L‘ọyọ

Ìjọba Àpapọ̀ Kò Gbẹ́sẹ̀lẹ̀ Lé Owó Tó Tọ́ Sáwọn Ìjọba Ìbílẹ̀ L‘ọyọ

Ìjọba àpapọ̀ kò gbẹ́sẹ̀lẹ̀ lé owó tó tọ́ sáwọn ìjọba ìbílẹ̀ l‘Ọyọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lórí ọ̀rọ̀ kan tó gbà gboro kan pé àgbẹjọrò àgbà orilẹ̀-èdè Naijiria, Abubakar Malami ti pàṣẹ fún gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo láti gba àwọn alága káńṣù ti wọ́n yọ nípò pada, Ìjọba Ọyọ ti fèsì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Nígbà tó ń sẹ̀rí ọ̀rọ̀ náà, Akọ̀wé ìkéde ìjọba ìpińlẹ̀ Oyo, Ọgbẹ́ni Taiwo Adisa ní, ìrọ tó jìnà sí òtítọ ni nítori pé òun kò tí ì rí lẹ́ta kankan tó jọ bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Malami.
Ó fí kún un pé kò sí ìgbà kankan tí Malami jáde láti sọ pé òun kọ lẹ́tà ránṣẹ́ si ìpínlẹ̀ Oyo, pẹ̀lú àfikún pé, ó se pàtàki ki àwọn akọ̀ròyìn máa ṣe ìwádìí wọ́n dáradára, ki wọ́n tó máa tan ìròyìn tí kò fi ìdí múlẹ̀ káàkiri.

Lórí àhesọ ọ̀rọ̀ kan tó sọ pé, ìjọba ìpinlẹ̀ Oyo kò rí owó gbà láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ fún àwọn ìjọba ìbilẹ̀, nítori pé àwọn Alága fìdíẹ ni wọ́n fi sí ìjọba Káńsù Adisa ní òfo ọjọ́ kejì ọjà ni ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

” Ẹni tí wọ́n bá nà ló yẹ kí ara máa ta, tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ kò bá rí owó gbà, ẹnu ìjọba ìpínlẹ̀ ni ẹ ó ti gbọ́ kìí ṣe ẹnu àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀. Nítorí náà, òfúùtù fẹ́ẹ̀tẹ̀ ni Ìròyìn tó ní àwọn Ìjọba ìbílẹ̀ ní Ọyọ kò rí owó tó tọ́ sí wọn gbà láti ọ̀dọ̀ Ìjọba àpapọ̀.”

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo