Home / Àṣà Oòduà / Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni
ifa

Kùtùkùtù Ìrèní Laó He Erè Nígbódù Oòni

Òní laó roko létí opón
Òla laó sákà lágbèrù
Kùtùkùtù ìrèní laó he erè nígbódù oòni
Káyáa múlé pontí
Kámú òdèdè rokà
Káfi agbada dínran
Àwèje wèmu nípón omodé wòyí lójú
Òrìsà lópabuké tán
Lódákún sábaro nídìí
Omo-ojo húnsáré gíríjo-gíríjo
Omo-ojo húnsáré gìrìjo-gìrìjo
Ilé-ifón kògba obàtálá
Èlàgboro kògba òrìsà
Ojúgboro ni tàfín
Èlàgboro ni tòrìsà
Omi níti ojú-omi rúwá
Èròyà wáàpon
Èròyà wáàmu
Rúkú-rùkù-rúkú niwón nse lókè ohùnkò
Erú kùnrin won nííjé bánakú
Erú bìnrin won nííjé wòrúkú
Dimúdimù aleìgbò
Okùnrin yàkàwú orí ìgbá
Ìgbá kòwó
Okùnrin yàkàwú kòsòkalè
Òní laóko igbó olú-kóókó-bojo
Òla laóko igbó olú-kóókó-bojo
Akogbó olú-kóókó-bojo tán
Apa ekùn kan mìnììjò-miniijo tínbe lábé ìtí
Wónní kí ákun-un
Kágbé oríirè fún obanídòó ejèrùwà-ìlèkè
Kágbé gègè àyàarè fún obaléyò ajòòrí Omo ajorí emi gbára
Kágbé gegelúge ìdíirè fun olúléhùnpejìgá Omo iná abara húta òjò palami okà se yèrìyèrì
Enití nbá perí obanídòó orí gbogbo amón-on fówon iwéréré-iwéréré
Enití nbá perí obaléyò ajòrí àyà gbogbo amón-on jìnwón igìrìrì-igìrìrì
Ènìyàn tí nbá perí olúléhùnpejìgá ìdí won yíò món-on lu agbè yàba ikunkun-ikunkun
Ogun obanídòó niná
Teléyò loòrùn
Ogun olúléhùnpejìgá logun Oba tínkówon iróro-iróro
Àpagbé awo ojó díáfún ojó
Àràngbé awo òòrùn díáfún
Tóbádi ojókan soso òjò
Yíóborí egbegbèrún òdá
Tóbá pawón tan
Apogun won ibíti-ibíti
Adífáfún olófin àyàngbo-àsè
Èyítí wónní kósáré losí òkè ohùnkò
Kólorèé jáwé abílè tíkòníkú wá
Ikú kò ikú kògbodò pa babaláwo
Àìsè àjà gbonhun
Húnró gbonhun lésè oba òrìsà
Kínni óní kíbi óyè lórí awo ?
Èjì-òyè òtító nikú yè lórí awo
ÈJÌ-ÒYÈ.
Ikú kòní pawá ní rèwerèwe ooo

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òyèkú bìwòrì

Òyèkú bìwòrì,Gbóró,gbóró,gìdì ? òyèkú b’ìwòrì?Ajan gbóró gìdìAdífáfún lájosìnOmo ab’oya ríreÈyí tio bo òrìsà obìnrin làÈròpo àti tòfàB’ifá bá..bíni níbèOya ni ko maa bo ~Translation ~ Òyèkú bìwòrìGbóró gbóró gìdìAjan gbóró gìdìCast ifá for lájosìnThe one that worship oya with blessingsThe one that is destined to worship oya to be successfulPeople going to ipo, People going to offaWhenever someone is born with this odù ifáMust worship òrìsà oya and take her as his or her priorityFor him or her to be ...