Home / Àṣà Oòduà / N kò leè fi ìdúnú mi pamọ́ lọ́jọ́ ìkómọ àwọn ìbẹta….Yinka Ayefele

N kò leè fi ìdúnú mi pamọ́ lọ́jọ́ ìkómọ àwọn ìbẹta….Yinka Ayefele

N kò leè fi ìdúnú mi pamọ́ lọ́jọ́ ìkómọ àwọn ìbẹta….Yinka Ayefele

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹ̀dá ò láròpin láyé, ṣé bí ó se wu Olúwa Ọba níí sọlá, fẹ́ni Ó wù ú,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ níbi tí t’ọba, tìjòyè, ọ̀tọ̀kùlú ìlú àti àwọn ìlúmọ̀ọ́ká olóṣèlú,ti péjú pésẹ̀ yẹ́ àwọn ìbẹta t’Ọ́lọ́run fi ta gbajúgbajà olórin Yinka Ayefele lọ̀rẹ níbi ìkómọ wọn.


Nínú oṣù keje ọdún 2019 ni Yinka Ayefele kò le pa oore náà mọ́ra tó sì tú ìròyìn ayọ̀ náà síta pé Ọlọ́run ṣe ìdílé òun lóore ńlá.
Níbi ìkómọ àwọn ìbẹta yìí, kìí ṣe ọ̀rọ̀ èrò diẹ̀ tabi wẹ́wẹ́, ẹsẹ̀ kò gbèrò síbẹ̀ àwọn lóókọ lóókì láwùjọ gan wá darapọ̀ níbi ayẹyẹ náà.


Ṣaájú ni àwọn èèyàn tí ń gbọ fìnrìnfìnrìn bíi pé Ìròyìn òfegè no tó sọ pé ìyàwó òǹkọrin yìí bímọ ṣùgbọ́n tí òun pẹ̀lú tètè bọ́sí ìgboro láti ṣàlàyé pé ìyàwó òun kò tíí bímọ. Ẹ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, n kò bí ìbẹta – Yinka Ayefẹlẹ.
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀rọ̀ náà di òhun, olórin yìí kò bo oore Ọlọ́run mọ́ra láti ìgbà tó ti kọ́kọ́ fi ojú àwọn ọmọ mẹ́ta náà hànde. Lára ọ̀nà ìdúpẹ́ rẹ̀ ni ìsìn ìkómọjáde tó wáyé lọ́jọ́ àìkú ,ọjọ́ kẹta oṣù Kọkànlá ọdún 2019.


Lọ́jọ́ ìkómọ náà, àwọn èèkàn ìlú péjú síbẹ̀. Pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú ni wọ́n sì fi ń yẹ́ ìyá, bàbá àti àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run naa sí.
Yinka Ayefele fi ìmọrírì rẹ̀ hàn sí àwọn tó wá síbi ìkómọ àwọn ẹ̀ta ọba ọmọ tó wọlé tọ ìdílé rẹ̀ wá.

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.