Home / Àṣà Oòduà / Pa Kasumu, ó dìgbà kan ná

Pa Kasumu, ó dìgbà kan ná

Kayode Odumosu,papòdà lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Kayode Odumosu tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Pa Kasumu ti juwọ́ ìgbẹyìn sáyé pé ó dìgbàkan.

”Èèyàn dáadáa ni wọ́n yàtọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ òṣèré tíátà.Ikú wọ́n jẹ́ eléyìí tó fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lẹ́mìí”

Yàtọ sí Mr Latin àwọn òṣèré míràn bí Foluke Daramola ti fi ìkéde ikú Pa Kasumu sí ojú òpó wọn ní Instagram pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn ikú rẹ̀.
Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kẹta ọdún 1953 ni wọ́n bí Kayode Odumosu ní ìlú Ìbàdàn.

Ọmọ Odogbolu ní ìpínlẹ̀ Ogun ni a gbọ́ pé Bàbá rẹ̀ jẹ́ tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Abeokuta.

Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀ eré sinimá tí àwọn èèyàn sì mọ́ ọ̀ gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtarìgì nínú awọn adẹrinposonu eré tíátà lédè e Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́ṣì.

Lọ́jọ́ Àìkú ní Ààrẹ àwọn òṣèré tíátà Yorùbá ní Nàìjíríà Bolaji Amusan Mr Latin fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn.

Ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta tí àìsàn ti ń bá Pa Kasunmu fínra,k kí ó tó wá já sí t’ọlọ́jọ́.

http://iroyinowuro.com.ng/2020/03/02/pa-kasumu-o-digba-kan-na/

About ayangalu

x

Check Also

ALÁÀFIN

Ó Pọ́dún Mẹ́ta Lónìí Tí Aláàfin Adéyẹmí Re Barà.

Kò sẹ́ni tí ó ju sáyé, gbogbo wa la ó dìtàn. Aláàfin Àtàndá ti kópa ti wọn, wọ́n ti lọ. Ọdún kẹta rèé tí Aláàfin Ọláyíwọlá ọmọ Adéyẹmí yíjú kúrò níhìn-ín, Ọláyíwọlá kọjú sáwọn aláṣekù, Baba bá wọn lọ. Iṣẹ́ tí wọ́n ṣe é lẹ̀ là ń sọ, tó dìròyìn. Bí a ti ń sọ ọ̀rọ̀ nípa Ọmọ Ìbírònkẹ́ lónìí, àsìkò ń bọ̀ tí àwọn kan náà ó sọ nípa tiwa. Kí layé á sọ nípa tèmi-tìrẹ? Ìlẹ̀pa dòdò kó ...