Home / Àṣà Oòduà / Àṣírí Pásìtọ̀ Tó Ń Fí Sọ́ọ̀si Ṣe Ọ̀gbà Wèrè Tú

Àṣírí Pásìtọ̀ Tó Ń Fí Sọ́ọ̀si Ṣe Ọ̀gbà Wèrè Tú

Àṣírí pásìtọ̀ tó ń fí sọ́ọ̀si ṣe ọ̀gbà wèrè tú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé biribiri òkuǹkùn ọ̀rọ̀ lójú ọmọ aádámọ̀ ,ìmọ̀lẹ̀ gbòò ni lójú Adẹ́dàá. Ní báyìí, Olùsọ́ àgùtàn Joseph Ojo, ní ọwọ ṣìnkún ọlọpàá ti mú fún lílo ilé ìjọsìn rẹ̀ tí ó wà ní àgbègbè Ijegun ìpínlẹ Eko gẹ́gẹ́ bi ẹ̀wọ̀n fún àwọn alárùn ọpọlọ àti àwọn tí wọ́n ní àrùn kan tàbi òmíràn.


Ìròyin sọ pé ọlọpàá mú Ojo lẹ́yìn ti ẹ̀ka ọlọpàá Isheri-Osun tú àwọn ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún sílẹ̀ nínú ilé ìjọsìn rẹ̀ ní ọjọ́rú lẹ́yìn tí àwọn àjọ kan ti kìí ṣe ti ìjọba ta ilé iṣẹ́ ọlọpàá lólobó.


Àbẹ̀wò sí àwọn ọlọ́pàá sílé ìjọ náà ní ọjọ́bọ sàfihàn pé àwọn ènìyàn kan wà lóríso bí ẹran àmúso tí àwọn míràn sì ń
sọ̀rọ̀ tí kò jọrawọn.


Ojo sàlàyé fún àwọn akọròyìn pé òun so àwọn ènìyàn náà mọ́lẹ nitórí ipò ti wọn wà, àti pé ọ̀pọ̀ wọ́n ni òbí wọ́n mú wá fún ìtúsílẹ̀ àti ìwòsàn.


O ní ” a so àwọn ènìyàn yìí mọlẹ̀ nítori ipò ti wọ́n wà, tí a ò bá so wọ́n mọ́lẹ̀ wọ́n á sálọ, wọ́n ti ko mi sí wàhálà sẹ́yìn, nítori náà ni mo ṣe so wọ́n tí ara wọ́n bá ti yá ni a máa ń tú wọ́n sílẹ̀.”
Pásítọ̀ Ojo ní, “Ibí kìí ṣe ilé ìwòsàn ti wọ́n ti ń wo àrùn ọpọlọ sùgbọ́n ọ̀pọ̀ wọ́n ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbé lọ sí ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń wo wèrè kí wọ́n tó gbé wọ́n wá síbi.”


“Bí osù mẹ́ta sí mẹ́rin ni a fi máa ń so wọ́n mọ́lẹ̀, àwọn ẹbí wọ́n sì ní yóó máa fún wọn lóunjẹ, àwọn ẹbí àwọn míràn máa ń wá lójoojúm, àwọn míràn ọsẹ̀-ọ̀sẹ̀, nígbà ti àwọn míràn ń gbé pẹ̀lú ẹbí wọ́n nínú ìjọ”
Ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n ti so mọ́lẹ̀ fún oṣù mẹ́jọ níbẹ̀, Adewale Adetona sàlàyé pé wọ́n jí òun gbé ni, àwọ́n ẹbí òun sì gbé òun wá sí ilé ìjọsin náà, ó ní kò dùn mọ́ òun láti máa gbé sọ́ọ̀sì.


Ẹ̀wẹ̀, ìyá Adewale Monsurat sàlàyé pé, fúnra òun ni òun gbé ọmọ náà wá sí ilé ìjọsìn ọ̀hún fún àdúrà, nítorí ó máa ń dójú ti ẹbí láàrin ìgboro.
Ìjọ ìbùkún rere ìwòsàn “Blessings of Goodness Healing Church” ni ijegun Isheri yìí ni àwọn ọlọ́pàá ti tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Bala Elkana tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn ọlọ́pàá ṣe ṣàlàyé.

About ayangalu

x

Check Also

IGP usman

Ọkùnrin tí àwọn adigunjalè yìnbọn mọ́ ní ọjà Bodija ṣì wà láyé — Ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá Ìròyìn òkèrè, bí ò lé, a dín.Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ṣàlàyé bí ìdigunjalè kan tí ìròyìn sọ pé ó gba ẹ̀mí èèyàn kan ṣe wáyé ní ọjà Bódìjà nílùú Ìbàdàn. Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Adéwálé Òṣífẹ̀sọ̀, sọ nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún pé lọ́jọ́ ẹtì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Ó ní arákùnrin kan, Abubakar Ibrahim, ni àwọn adigunjalè kọlù ní nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n sì yìnbọn mọ́ ọ kí wọ́n ...