Home / Àṣà Oòduà / Aregbesola sedaro Hon. Makinde to doloogbe

Aregbesola sedaro Hon. Makinde to doloogbe

Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ranse ibanikedun si idile Hon Makinde Oladejo Samson to doloogbe lojo Aiku to koja yii, 27/12/15. Hon Makinde, omo egbe PDP, to je okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle Osun lo jade laye leni odun mejidinlaadota (48) leyin aisan ranpe.

Iku Hon Makinde, eni ti n soju Aarin-gbungbun Ife nile igbimo asofin, ni gomina Aregbe se alaye re gege bi ajalu nla eleyii ti enikeni ko reti rara ni asiko yii. Ogbeni Aregbe ko sai tun ranse ibanikedun si egbe PDP ati awon eniyan ti Makinde n soju.

“Bi o tile je wi pe ibanuje ni lati padanu odo bi Onarebu Makinde, sugbon ohun to daju niku; gbogbo wa la dagbada iku. Ki Olorun Oba mimo ba wa te si afefe rere,” Ogbeni Aregbe fi kun leta ibanikedun re bee.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Sanwo olu

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré Yínká Àlàbí Ile-iṣẹ Aṣẹ ati Iṣakoso Pajawiri ti Ipinle Eko sọ pe awọn ti setan lati dahun si awọn ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko laarin isẹju marun-un pere.Olùdarí Àgbà fún ilé-iṣẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Femi Giwa, sọ èyí ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú awọn oniroyin ní ìlú Èkó.Giwa sọ pé àfojúsùn ilé-iṣẹ́ náà ni láti dín àkókò tó wà láàrín ìyè àti ikú kù nípa rírí dájú pé ìdáhùn náà wáyé láàrín ìṣẹ́jú ...