Home / Àṣà Oòduà / Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn

Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn

Àwọn obìnrin tọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn

Ọjọ́ kẹjọ ọdọọdún ni àyájọ́ àwọn obìnrin lágbàáyé níbi tí gbogbo àgbáyé tí ń kọjú sí àwọn obìnrin láti yòǹbó àwọn iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n gbé ṣe láì nọ́ọ́ní onírúurú ìpèníjà, ẹ̀dùn ọkàn àti Ìlàkàkà wọn fún àṣeyọrí gbogbo
Ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin pẹ̀lú ìdọ́gba pẹ̀láwọn ọkùnrin ló gbòde gẹ́gẹ́ bíi ohun òjútáyé lásìkò àjọyọ̀ àyájọ́ obìnrin lágbàáyé ti ọdún yìí.

Àkọmọ̀nà àyájọ́ náà fún ọdún yìí ni “ajàfẹ́tọ̀ ìbáradọ́gba ni mí: mímú ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ṣẹ.”

Nínú ọ̀rọ̀ tiwọn, àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé rọ àwọn èèyàn gbogbo láti jí gìrì gbógun ti àwọn ìpèníjà sísọ àìdọ́gba láàrin ẹ̀yà ẹ̀dá gbogbo.

Nínú ọkàn ò jọ̀kan ọ̀rọ̀ tí wọ́n ṣọ ní ìrántí àyájọ́ yìí, àwọn obìnrin ní oríṣìríìṣí Ìlànà iṣẹ́ ajé gbogbo sọ̀rọ̀ lórí ìpèníjà tí wọ́n ń dojúkọ; paàpá jùlọ láàrin àwọn ọkùnrin lẹ́nu iṣẹ́ ajé gbogbo léyìí tí ò jẹ́ adínàgboòkú.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo