Home / Àṣà Oòduà / Ayédèrú ni ‘plate number Chief Whip’ Kano – FRSC

Ayédèrú ni ‘plate number Chief Whip’ Kano – FRSC

Iroyin asise nomba moto asofin ilu Kano, Ogbeni Ayuba Durum ran kaakiri bi ina inu oye, paapaa julo lori ero ayelujara.


Eyi wa ya gbogbo aye lenu pe se bee ni awon ajo FRSC tii se adari eto irinna ati awon ohun to ro mo moto ya olodo to ni?
Awon eniyan ni asise ko tile ni oga, se ko ye ki won rii nigba ti o jade ni?
Awon kan ni bi dereba moto ko ba tile ka iwe, oga re n ko, won ni se oun naa ko ki n wo ara moto rara ni?


Eyi lo mu ki agbenuso ajo FRSC da awon ara ilu lohun pe awon ti se ayewo finni-finni lori ibi ti nomba naa gba jade.
Won ni ko gba odo awon jade ni eyi ti o mu ki oga patapata ajo naa, Ogbeni Boboye Oyeyemi naa dahun pe ona ayederu ni nomba naa gba waye.
Alaye awon ajo FRSC yii tun wa dabi igba ti eniyan “yinbon si ilu nla”.
Gbogbo aye tun wa denu bo awon asofin kaakiri, se Yoruba bo “won ni eru kan ni mu ni bu igba eru”.
Awon ara ilu ni bawo ni awon asofin se tun maa je arufin. Won ni o ye ki ijiya to nipon waye lori ibi ti ayederu naa gba waye.

http://iroyinowuro.com.ng/2019/11/03/ayederu-ni-plate-number-chief-whip-kano-frsc/

About ayangalu

One comment

x

Check Also

Sanwo olu

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré Yínká Àlàbí Ile-iṣẹ Aṣẹ ati Iṣakoso Pajawiri ti Ipinle Eko sọ pe awọn ti setan lati dahun si awọn ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko laarin isẹju marun-un pere.Olùdarí Àgbà fún ilé-iṣẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Femi Giwa, sọ èyí ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú awọn oniroyin ní ìlú Èkó.Giwa sọ pé àfojúsùn ilé-iṣẹ́ náà ni láti dín àkókò tó wà láàrín ìyè àti ikú kù nípa rírí dájú pé ìdáhùn náà wáyé láàrín ìṣẹ́jú ...