Home / Àṣà Oòduà / Ẹgbẹ́ Shiites wọ́de l’Abuja, wọ́n jó Àsìá Amẹ́ríkà

Ẹgbẹ́ Shiites wọ́de l’Abuja, wọ́n jó Àsìá Amẹ́ríkà

Ẹgbẹ́ Shiites wọ́de l’Abuja, wọ́n jó Àsìá Amẹ́ríkà

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, bá a se n pàkan, nìkan ń rú
Àwọ́n ọmọ ẹgbẹ́ “Islamic Movement of Naigeria” (IMN) tí gbogbo ènìyàn mọ sí Shi’ites lọ́jọ́ ajé ti ya sí ìgboro lágbègbè ilé ìtajà Bannex ni Wuse nílú Abuja láti wọ́de nítorí Olórí ọmọ ogun Iran Quasm Soleimani ti àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà pa lọ́jọ́ Ẹtì tó kọjá.

Bákan náà ni wọ́n pè fún ìtúsilẹ̀ adarí wọ́n Sheikh Ibraheem El-Zakzeky àti ìyàwó rẹ̀ Zeenat tí wọ́n wà ni àhámọ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Awọ́n olùfẹ̀hónú hàn náà bọ́ si ìgbòro Abuja tí wọ́n sì ń pariwo àwọn orin ọ̀tẹ̀ bí ” Iku ni fún Amẹ́ríkà”

Bákan náà ni wọ́n dáná sun àsìá orílẹ́èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n sì gbé àwọn àkọle tó bẹnu àtẹ lu pípa tí Amẹ́ríkà pa olóri ọmọogun Iran sọ́wọ́.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.