Home / Àṣà Oòduà / Ìjọba ti ayédèrú ilé ọmọ aláìlóbìí pa, ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira

Ìjọba ti ayédèrú ilé ọmọ aláìlóbìí pa, ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira

Ìjọba ti ayédèrú ilé ọmọ aláìlóbìí pa, ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn aláṣẹ tọ́rọ̀ kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti kó àgádágodo sílẹ̀kùn ilé ọmọ aláìóbìí kan tí kò ní wè é òfin ní ìpínlẹ̀ Kaduna, tí wọ́n sì tú ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sílẹ̀.

Ọjọ́ orí àwọn ọmọ náà wà láàrin ọdún mẹ́ta sí méjìlá.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano, DSP Abdullahi Haruna sọ fún akọ̀ròyìn pé, ó tó ọmọdé mọ́kàndínlógún táwọn tú sílẹ̀ nílé àwọn ọmọ aláìóbìí Du Merci nílùú Kano.

Bákan náà ni Abdullahi sọ pé, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tún tú àwọn mẹ́jọ mìíràn sílẹ̀ nílé àwọn ọmọ aláìóbìí Du Merci tó wà nílùú Kaduna.

Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ pé, eléyìí ṣeéṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àjọ NAPTIP tó ń gbógun ti fífi èèyàn ṣe òwò ẹrú lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ní, ayédèrú ilé ọmọ aláìóbìí nibi táwọn ti tú àwọn ọmọdé náà sílẹ̀.

Olùdámọ̀ràn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Fatima Abdullahi Dala, tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé Du Merci ti wà fún bí ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n láì níwèé òfin.

Ó wá rọ àwọn èèyàn Kano láti fi tó Ìjọba létí, tí wọ́n bá ṣàkíyèsí irú ilé ọmọ aláìóbìí bẹ́ẹ̀ lágbègbè wọn.

http://iroyinowuro.com.ng/2020/01/10/ijoba-ti-ayederu-ile-omo-alailobii-pa-omode-metadinlogbon-gbominira/

About ayangalu

x

Check Also

Sanwo olu

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré Yínká Àlàbí Ile-iṣẹ Aṣẹ ati Iṣakoso Pajawiri ti Ipinle Eko sọ pe awọn ti setan lati dahun si awọn ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko laarin isẹju marun-un pere.Olùdarí Àgbà fún ilé-iṣẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Femi Giwa, sọ èyí ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú awọn oniroyin ní ìlú Èkó.Giwa sọ pé àfojúsùn ilé-iṣẹ́ náà ni láti dín àkókò tó wà láàrín ìyè àti ikú kù nípa rírí dájú pé ìdáhùn náà wáyé láàrín ìṣẹ́jú ...