Home / Àṣà Oòduà / M C Oluo̩mo̩ fo̩wó̩ o̩lá gbáwa lójú – NURTW

M C Oluo̩mo̩ fo̩wó̩ o̩lá gbáwa lójú – NURTW

MC Oluo̩mo̩ fo̩wó̩ o̩lá gbáwa lójú – NURTW
Láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí
Oro ti gbogbo ara ilu ni o ti ku regbe ti o si ti di ohun igbagbe ni o tun n rugbo ni ibere ise yii laarin Musiliu Akinsanya ati Adekunle Lawal ti gbogbo eniyan mo si Kunle Poly.


Ikolura-eni yi ti n rugbo bo laarin awon mejeeji ki o to di pe olobo ta awon olopaa ti won si sare lo fi owo sinkun ofin ko awon osise NURTW mejidinlaadota.


Lara awon ti awon olopaa ko yi lo n ba awon oniroyin soro pe awon ko tile ba ti ija wa rara. Won ni M C Oluomo to je oga awon ni ipinle Eko lo pe ipade ti awon se wa, awon ko mo pe panpe lo de sile fun awon.
Awon afunrasi yii ni ti a ba wo awon ti won ko daadaa, a maa rii pe awon eniyan Kunle Poly lo po ju.


Awon afunrasi naa ni inu awon ko dun si iwa ti Oluomo wu rara nitori pe awon naa ko ki n se omo Esu, bi ilu se maa toro lo je awon naa logun.
Olu ileese NURTW to wa ni ilu Agege ni awon olopaa ti lo ko awon eniyan naa.


Komisona Olopaa ni ipinle Eko, Ogbeni Hakeem Odumosu ni awon maa fi won sile ni kete ti awon ba ti pari iwadii lori won.

About ayangalu

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...