Home / Àṣà Oòduà / Maryam Sanda ṣì wà lẹ́wọ̀n, Buhari kò dáa sílẹ̀.

Maryam Sanda ṣì wà lẹ́wọ̀n, Buhari kò dáa sílẹ̀.

Iléeṣẹ́ Ààrẹ ló sọ pé Ìròyìn tó ń jà rànyìnrànyìn kiri pé Ààrẹ Muhammadu Buhari tí darí jin arábìnrin náà kìí ṣe òtítọ́ rárá.Ki àwọn èèyàn kọtí ọ̀gbọin sí i.
Ní oṣù kínní ọdún yìí ni ilé ẹjọ́ dá arábìnrin Maryam Sanda lẹ́bi ikú pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn gígún ọkọ rẹ̀ pa tí wọ́n fi kàn án.

Amúgbálẹ́ẹ̀gbẹ́ fún Ààrẹ Buhari lórí ọ̀rọ̀ Ìròyìn ayélujára, Bashir Ahmad ló fi síta lójú òpó twitter rẹ̀ pé, ara ọ̀nà láti ba orúkọ rere tí Ààrẹ ti ní lórí ètò ìdáríjì fáwọn ẹlẹ́wọ́n tó wáyé láìpẹ́ yìí lọ́nà àti mú àdínkù bá àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó kún fọ́fọ́ lórílẹ̀-èdè yìí.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo