Home / Àṣà Oòduà / Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀

Ọ̀daràn kan fi tipá wọ ààfin Ọ̀ọni ilé ifẹ̀

A kìí gbélé ẹni ká fi ọrùn rọ́ ni a ti ń gbọ́ tipẹ́ tipẹ́, sùgbọ́n kín wá ni ká ti pe tirúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà yìí tó wáyé ní ààfin Ọọ̀nirìṣà Ọba Adéyẹyè Ògúnwùsì,ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun níbi tí àwọn èèyàn ìlú Ilé Ifẹ̀ ni àwọn ti ń gbọ́ ìró ìbọn ní kíkàn kíkan ní ilé Oòduà tíí ṣe ààfin Ọọ̀nirìṣà Ilé Ifẹ̀, Ọba Adéyẹyè Ògúnwùsì .

Eléyìí ló ṣì mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ìlú ìṣèǹbáyé náà ó máa kó àyà sókè lórí àlàáfíà Ọọ̀nirìṣà Adéyẹyè Ògúnwùsì.

Nígbà tí gbogbo rẹ̀ yóó fi rọlẹ̀ ni ìròyìn jáde pé àwọn èèyàn mẹ́ta kan gbìyànjú láti fi ipá wọ ààfin nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Nígbà tí wọ́n dé ìloro àkọ́kọ́ ní ààfin Ọọ̀nirìṣà ní àwọn ẹ̀ṣọ́ bèèrè ohun tí wọ́n wá ṣe, tí méjì nínú wọn sì bẹ́ sílẹ̀ nínú mọ́tò tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.

Ẹnì kẹta wọn tó wa ọkọ̀ náà ni wọ́n ní ó fi ọkọ̀ náà já ìloro kínní àti ìkejì pẹ̀lú èròńgbà láti wọ ìloro kẹta níbi tí Kábíyèysí àrólé Oòduà, Ọọ̀nirìṣà Ọba Ògúnwùsì ń gbé, ṣùgbọ́n àwọn agbófinró tó ń ṣọ́ ààfin náà bá ya bò ó.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí alákòóso ọ̀rọ̀ ìròyìn fún Ọọ̀nirìṣà, Kọmureedi Ọlafare ṣe ṣàlàyé fún akọròyìn, Ajá kan tí wọ́n ní arákùnrin náà gbé sínú ọkọ̀ tí ó tú sílẹ̀, ni àwọn agbófinró ń lé kiri.

Ìró ìbọn tí wọ́n sì ń yìn sí ajá náà níbi tí wọ́n ti ń lé e kiri làwọn aráàlú gbọ́ tí wọ́n fi rò pé bóyá àwọn adigunjalè ló wọ ààfin.

Arákùnrin náà ní wọ́n ní ó wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí tí ìròyìn sì ń jẹ́ kó di mímọ̀ pé ó ti bá wọn lálejò ní ẹ̀ka ọ̀tẹ̀lẹ̀múyẹ iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní Òṣogbo.

Nínú ọ̀rọ̀ tó bá iléeṣẹ́ Ìròyìn kan ní ìlú Ọṣogbo sọ, alukoro fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, nínú àlàyé rẹ̀ dárúkọ arákùnrin náà gẹ́gẹ́ bí i Daramọla Wasiu.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

mko

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola À ṣẹ kò sééyan táyé ò lé bá ṣọ̀tá, ó tún hàn pé wọ́n le bínú òkú ọ̀run , yàtọ̀ sèèyan tí wọ́n jọ ń wà láyé. À bí kín ní ká tí pé tàwọn kọ̀lọ̀rànsí t’ọ́wọ́Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ báyìí pé wọ́n digunjalè sọsẹ́ nílé olóògbé Olóyè Moshood Abíọ́lá tó wà ní Ìkẹjà nílùú Èkó níbi tí wọ́n ti jí nǹkan tó tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lọ. Abíọ́lá ló jáwé olúborí ...