Home / Àṣà Oòduà / Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá fún mi nígbà tí mo dùbúlẹ̀ àìsàn…Taiwo Hassan

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá fún mi nígbà tí mo dùbúlẹ̀ àìsàn…Taiwo Hassan

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sá fún mi nígbà tí mo dùbúlẹ̀ àìsàn…Taiwo Hassan, Ògògó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí ẹyìn ọ̀rọ̀ ò bá ì pọ́n, ẹnìkan kìí sí i ,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí bí gbajúgbajà òṣèré sinimá àgbéléwò,n nì, Taiwo Hassan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ògògó ti padà ṣọ̀rọ̀ lori àárẹ̀ tó ṣe é fún odindin ọdún mẹ́jọ láti ọdún 2004 títí di 2012.

Nigba ti o n ṣe aisan naa, oriṣiriṣi iroyin ofege lo gbalukan nipa nnkan to n ṣe oṣere naa.

Nigba ti awọn kan n sọ pe o ni arun HIV ni awon kan ni egbo igi oloro lo tu sii ninu.
Ṣùgbọ́n àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré náà ti ṣàlàyé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ síi nígbà náà fún aráyé

Ògògó ní nínú ààwẹ Ramadan ọdún 2004 ni òun mọ̀ pé òun ní àrùn ọgbẹ́ẹnú tí wọ́n pé ní “Ulcer”.

Ó ní òun lò tó oṣù méje tí òun ń kí ìrun lórí ìjókòó nítorí pé òun kò tó ẹrù Ọlọ́run tó ń dìde dúró láti kí ìrun.

Ògògó ní òun ní láti pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ òun nígbà tíròyìn ń káàkiri pé òun gbé egbòogi olóró ni àbí pé òun kó àrùn HIV ni.

T’ònti pé ẹlẹsin Muslumi, Kristẹni àti ìṣẹ̀ṣe ń gbàdúrà fún un, àwọn orẹ àti ìyàwó rẹ̀ padà fi sílẹ̀ lọ nígbà tí ìṣòro náà pọ̀.

Ògògó ní òun padà fẹ́ obìnrin tó dúró ti òun nígbà ìṣòro náà, obìnrin náà sì ti bímọ méjì fún òun báyìí.

Ṣé obìnrin kúkú kọ́kọ́ bímọ fún ni kò pé kó dúró ti ni nígbà ìṣoro .

Taiwo Hassan gba àwọn tó bá ń la ìṣòro kan kọjá lásìkò yìí láti túbọ̀ súnmọ́ Ọlọ́run kí wọ́n kún fún àdúrà.

Ó ní kò sí ìṣòro tó ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kò ní lópin tí èèyàn bá ní sùúrù tó dẹ̀ ń gbàdúrà.

About ayangalu

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.