Home / Awọn Iroyin Agbegbe / Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde orúkọ àwọn aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn rẹ̀
Amotekun

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde orúkọ àwọn aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn rẹ̀

Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde orúkọ àwọn aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Olójú kò nì-ín lajúẹ̀ sílẹ̀, kí tàlùbọ̀ ó yí wọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni bí èèyàn bá joyè Arẹ̀kú, ó yẹ kó lè pitú lábẹ́ agọ̀.

Èyí ló mú kí àwọn ìjọba ní ìhà Yorùbá àti agbègbè rẹ̀ gbé ikọ̀ aláàbò
Àmọ̀tẹ́kùn kalẹ̀ léyìí tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà jẹ́ ọkàn lára wọn.

Ní báyìí, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kéde pé orúkọ àwọn tó yege láti darapọ̀ mọ́ ikọ̀ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún ti jáde.

Nínú àtẹjáde tí adarí ikọ̀ náà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ajibola Kunle Togun, fi léde, ó ní gbogbo àwọn tó forúkọ sílẹ̀ sí ojú òpó tí Ìjọba gbé kalẹ̀ fún ikọ̀ náà láti lọ wo orúkọ wọn.

Ó ní “kí gbogbo àwọn tó yege nínú ìforúkọsílẹ̀ ọ̀hún lọ sí ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àwọn olùkọ́, Emmanuel Alayande, tó wà ní ìlú Ọ̀yọ́ láago mẹ́sàn Òwúrọ̀ lọ́jọ́ kẹta, oṣù Kọkànlá, ọdún 2020, fún ètò ìforúkọsílẹ̀ ní kíkún.”

Ó fi kún un pé ìgbaradì àti ìdánilẹ́kọ́ọ̀ fún àwọn èèyàn náà yóó wáyé fún ọ̀sẹ̀ méjì gbáko.
Àtẹjáde ọ̀hún tẹ̀síwájú pé kí àwọn èèyàn náà mú sòkòtò pélébé aláwọ̀ búlúù, aṣọ funfun àti bàtà káńfàsì tó ṣe é sáré lọ́wọ́.
Kò tán síbẹ̀, ó tún ní kí wọ́n kó ike ìwẹ̀, àgó ìmumi, síbí, abọ́ oúńjẹ àti ìgbálẹ̀ lọ́wọ́.

Adarí ikọ̀ náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí àwọn tí orúkọ wọn kò jáde má ṣe ìyọnu láti yọjú sí ọgbà iléèwé tí ìdánilẹ́kọ́ọ̀ àti ìgbaradì náà yóó ti wáyé.

About asatiwa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*