Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì fèsì lórí ìwọ́de EndSARS
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba orílẹ̀-èdè United Kingdom, ti fèsì lórí ìwé ẹ̀sùn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà fọwọ́ sí, tí wọ́n sì fi ránṣẹ́ síi.
Ìwé náà ló ń ké sí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé tó wà nínú àjọ Commonwealth, láti fi ‘ ìyà’ jẹ àwọn Olórí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ìbáwí, fún ẹnikẹ́ni nínú wọn tó lọ́wọ́ nínú títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú, gẹ́gẹ́ bí òfin àjọ náà ṣe sọ.
Ọmọ Nàìjíríà bíi okòólérúgba ó dín díẹ̀ (219,665) ló fi ọwọ́ sí ìwé ẹ̀sùn náà lọ sọ́dọ̀ọ Ìjọba UK.
Ilé Aṣòfin Orílẹ̀-ede UK sọ pé, ominú ńkọ òun lórí rògbòdìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de ENDSARS, àti pé àwọn ṣì ń dúró de ìwádìí tí Ìjọba Nàìjíríà yóó ṣe lórí ẹ̀sùn ìfìyàjẹni tí aráàlú fi kan àwọn ọlọ́pàá.
Ìwé ẹ̀sùn tó bá ti ní ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn èèyàn tó fọwọ́ sí i , ní ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK má ń jíròrò lé lórí, ìwé ẹ̀hónú ENDSARS yìí sì ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba.
Àmọ́ṣá, wọ́n ní àwọn kìí sọ ìgbésẹ̀ tí àwọn yóó gbé lórí àwọn ìwé ẹ̀sùn náà ní gbangba.