Home / Àṣà Oòduà / Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi

Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi

Fìdáù Ajímọ̀bi, ẹbí nìkan ní wọ́n ń retí–Ẹbí Ajímọ̀bi

Ṣé wọ́n ní kìí jẹ́ ti baba t’ọmọ, kó mọ́ ní ààlà. Èyí ló díá fún bí àwọn ẹbí olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi tí sàlàyé pé ,kí àwọn olùkẹ́dùn, ó má wulẹ̀ dààmu yọjú sí bi fìdáù, ní ìbámu pẹ̀lú n tí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì n sọ , bí ó ti jẹ́ pé òní, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Keje, ni àdúrà ọjọ́ kẹjọ yóó wáyé fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀rí tó di olóògbé, Sẹ́nétọ̀ Isiaka Abíọ́lá Ajímọ̀bi.

Ètò àdúrà náà, Fìdáù, wà ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àti ìṣẹ ẹ̀sìn Islam. Ìdílé olóògbé sọ nínú Ìkéde tó fi síta fún ètò àdúrà náà pé, ẹbí Ajímọ̀bi nìkan ni ètò àdúrà náà wà fún, nítorí òfin tó rọ̀ mọ́ ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Ṣùgbọ́n ṣá, wọ́n ní àwọn aráàlú yóó ní àǹfààní láti wo bí ètò àdúrà náà bá ṣe ń lọ lórí amóhùnmáwòrán àti lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Ọjọ́ kẹẹdọgbọn, oṣù Kẹfà, ọdún 2020, ni Abíọ́lá Ajímọ̀bi kú, síléèwòsàn First Cardiologist, tó wà nílùú Èkó, lẹ́yìn tó ní àrùn Kofi-19.

Ẹni àádọ́rin ọdún olóògbé Abíọ́lá Ajímọ̀bi ko tó tẹ́rí gbaṣọ.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Òyèkú bìwòrì

Òyèkú bìwòrì,Gbóró,gbóró,gìdì 📿 òyèkú b’ìwòrì📿Ajan gbóró gìdìAdífáfún lájosìnOmo ab’oya ríreÈyí tio bo òrìsà obìnrin làÈròpo àti tòfàB’ifá bá..bíni níbèOya ni ko maa bo ~Translation ~ Òyèkú bìwòrìGbóró gbóró gìdìAjan gbóró gìdìCast ifá for lájosìnThe one that worship oya with blessingsThe one that is destined to worship oya to be successfulPeople going to ipo, People going to offaWhenever someone is born with this odù ifáMust worship òrìsà oya and take her as his or her priorityFor him or her to be ...