Home / Àṣà Oòduà / Ìjo̩ba máa gbé pé̩ré̩gi kaná pè̩lú àwo̩n oníròyìn ìdàlúrú – Lai Mohammed

Ìjo̩ba máa gbé pé̩ré̩gi kaná pè̩lú àwo̩n oníròyìn ìdàlúrú – Lai Mohammed

Minisita fun eto iroyin ati asa ni orileede yii, Alhaji Lai Mohammed ni ijoba apapo ko ni gba ki awon kan fi iroyin aboosi da ilu ru.


O ni “oloju ko ni laju re sile ki talubo woo”. O ni aseju awon ti won pe ara won ni aja fun eto omoniyan ti po ju.


O ni orisiirisii iroyin to le da ilu ru, to le da irewesi si okan awon to n femi sise ilu ni won n gbe jade, paapaa lori ero ayelujara.
Minisita fi ibinu soro naa pe “esinsin won n je elegbo bayii, pe ki enikankan ma se soro nigba ti elegbo naa ba bere si ni je esinsin”.


Minisita ni awon topa awon onise ibi naa de bi wi pe awon kan je omo orileede yii ti won si n tafa lati oke okun. O ni “bi aja won ba lo ogun odun lori ile,eran ogun si ni”.

Lai Mohammed ni asiko ti ilu tile wa bayii lagbara die, o ni bi awon se n koju ajakale arun ti n ba agbaaye ja ki o ma se po ju ni Naijiria ni awon n fi egbe oju kan wo ipalara arun naa lori oro aje, awon ko pa eto aabo ti bee tun ni awon kan tun n paro fun awon ara ilu pelu iroyin eke.


Lai Mohammed ni ki awon miran to ba n gbero idaluru bee tete lo so ewe agbeje mowo.

Ìjo̩ba máa gbé pé̩ré̩gi kaná pè̩lú àwo̩n oníròyìn ìdàlúrú – Lai Mohammed
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

About ayangalu

One comment

x

Check Also

Orun Ire Ooooo

ERIN WOOOOOOO. Iku da Oro iku shei’ika, Iku mu eni rere lo.